Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 114 - Yoruba Bible


Orin Ìrékọjá

1 Nígbà tí Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, tí àwọn ọmọ Jakọbu jáde kúrò láàrin àwọn tí ń sọ èdè àjèjì,

2 Juda di ilé mímọ́ rẹ̀, Israẹli sì di ìjọba rẹ̀.

3 Òkun rí i, ó sá, Jọdani rí i, ó pada sẹ́yìn.

4 Àwọn òkè ńláńlá ń fò bí àgbò, àwọn òkè kéékèèké ń fò bí ọmọ aguntan.

5 Kí ló dé, tí o fi sá, ìwọ òkun? Kí ló ṣẹlẹ̀ tí o fi pada sẹ́yìn, ìwọ Jọdani?

6 Ẹ̀yin òkè ńlá, kí ló dé tí ẹ fi fò bí àgbò? Ẹ̀yin òkè kéékèèké, kí ló ṣẹlẹ̀ tí ẹ fi fò bí ọmọ aguntan?

7 Wárìrì níwájú OLUWA, ìwọ ilẹ̀, wárìrì níwájú Ọlọrun Jakọbu.

8 Ẹni tí ó sọ àpáta di adágún omi, tí ó sì sọ akọ òkúta di orísun omi.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan