O. Daf 113 - Yoruba BibleYíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀ 1 Ẹ yin OLUWA! Ẹ yìn ín, ẹ̀yin iranṣẹ OLUWA. Ẹ yin orúkọ OLUWA. 2 Kí á yin orúkọ OLUWA, láti ìsinsìnyìí lọ títí laelae. 3 Láti ìlà oòrùn títí dé ìwọ̀ oòrùn, kí á máa yin orúkọ OLUWA. 4 OLUWA ju gbogbo orílẹ̀-èdè lọ, ògo rẹ̀ sì ga ju ọ̀run lọ. 5 Ta ló dàbí OLUWA Ọlọrun wa, tí ó gúnwà sí òkè ọ̀run, 6 ẹni tí ó bojú wo ilẹ̀ láti wo ọ̀run ati ayé? 7 Ó gbé talaka dìde láti inú erùpẹ̀, ó sì gbé aláìní sókè láti orí eérú, 8 láti mú wọn jókòó láàrin àwọn ìjòyè, àní, àwọn ìjòyè àwọn eniyan rẹ̀. 9 Ó sọ àgàn di ọlọ́mọ, ó sọ ọ́ di abiyamọ onínúdídùn. Ẹ máa yin OLUWA. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria