O. Daf 112 - Yoruba BibleAyọ̀ Ẹni Rere 1 Ẹ yin OLUWA! Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA, tí inú rẹ̀ sì dùn lọpọlọpọ sí òfin rẹ̀. 2 Àwọn arọmọdọmọ rẹ̀ yóo jẹ́ alágbára láyé, a óo sì bukun ìran ẹni tí ó dúró ṣinṣin. 3 Ọlá ati ọlà yóo wà ní ilé rẹ̀, Òdodo rẹ̀ wà títí lae. 4 Ìmọ́lẹ̀ yóo tàn fún olódodo ninu òkùnkùn, olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, aláàánú ni, a sì máa ṣòdodo. 5 Yóo máa dára fún ẹni tí ó bá lójú àánú, tí ó sì ń yáni ní nǹkan, tí ó ń ṣe ẹ̀tọ́ ní gbogbo ọ̀nà. 6 A kò ní ṣí olódodo ní ipò pada lae, títí ayé ni a óo sì máa ranti rẹ̀. 7 Ìròyìn ibi kì í bà á lẹ́rù, ọkàn rẹ̀ dúró ṣinṣin, ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA. 8 Ọkàn rẹ̀ a máa balẹ̀, ẹ̀rù kì í bà á, níkẹyìn, èrò rẹ̀ a sì máa ṣẹ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. 9 Ó lawọ́, á máa ṣoore fún àwọn talaka, òdodo rẹ̀ wà títí lae, yóo di alágbára, a óo sì dá a lọ́lá. 10 Ìbànújẹ́ yóo bá eniyan burúkú nígbà tí ó bá rí i. Yóo pa eyín keke, yóo pòórá, ìfẹ́ rẹ̀ yóo sì di asán. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria