O. Daf 111 - Yoruba BibleYin OLUWA 1 Ẹ yin OLUWA! N óo dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA tọkàntọkàn, láàrin àwọn olódodo, ati ní àwùjọ àwọn eniyan. 2 Iṣẹ́ OLUWA tóbi, àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ sí i sì ń wá a kiri. 3 Iṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá, ó sì lógo, òdodo rẹ̀ sì wà títí lae. 4 OLUWA mú kí á máa ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, olóore ọ̀fẹ́ ni OLUWA, àánú rẹ̀ sì pọ̀. 5 A máa pèsè oúnjẹ fún àwọn tí wọn bẹ̀rù rẹ̀, a sì máa ranti majẹmu rẹ̀ títí lae. 6 Ó ti fi agbára iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn eniyan rẹ̀, nípa fífún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. 7 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tọ́, ó sì tọ̀nà, gbogbo ìlànà rẹ̀ sì dájú. 8 Wọ́n wà títí lae ati laelae, ní òtítọ́ ati ìdúróṣinṣin. 9 Ó ṣètò ìràpadà fún àwọn eniyan rẹ̀, ó fi ìdí majẹmu rẹ̀ múlẹ̀ títí lae, mímọ́ ni orúkọ rẹ̀, ó sì lọ́wọ̀. 10 Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, gbogbo àwọn tí ó bá ń tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, á máa ní ìmọ̀ pípé. Títí lae ni ìyìn rẹ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria