O. Daf 110 - Yoruba BibleOLUWA ati Àyànfẹ́ Ọba Rẹ̀ 1 OLUWA wí fún oluwa mi, ọba, pé, “Jókòó sí apá ọ̀tún mi, títí tí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” 2 OLUWA yóo na ọ̀pá àṣẹ rẹ tí ó lágbára láti Sioni. O óo jọba láàrin àwọn ọ̀tá rẹ. 3 Àwọn eniyan rẹ yóo fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀, lọ́jọ́ tí o bá ń kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ lórí òkè mímọ́. Àwọn ọ̀dọ́ yóo jáde tọ̀ ọ́ wá bí ìrì òwúrọ̀. 4 OLUWA ti búra, kò sì ní yí ọkàn rẹ̀ pada, pé, “Alufaa ni ọ́ títí lae, nípasẹ̀ Mẹlikisẹdẹki.” 5 OLUWA wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, yóo rún àwọn ọba wómúwómú ní ọjọ́ ibinu rẹ̀. 6 Yóo ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, ọpọlọpọ òkú ni yóo sì sùn ninu wọn; yóo sì run àwọn ìjòyè káàkiri ilẹ̀ ayé. 7 Ọba yóo mu omi ninu odò ẹ̀bá ọ̀nà, nítorí náà yóo sì gbé orí rẹ̀ sókè bí aṣẹ́gun. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria