O. Daf 11 - Yoruba BibleOLUWA ni Igbẹkẹle Àwọn Olódodo 1 OLUWA ni mo sá di; ẹ ṣe lè wí fún mi pé, “Fò lọ sórí òkè bí ẹyẹ; 2 ẹ wo àwọn eniyan burúkú bí wọ́n ti kẹ́ ọfà; wọ́n fa ọrun; wọ́n sì fi òkùnkùn bojú láti ta olódodo lọ́fà. 3 Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́, kí ni olódodo lè ṣe?” 4 OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀, ìtẹ́ rẹ̀ wà lọ́run; OLUWA ń kíyèsí àwọn ọmọ eniyan, ó sì ń yẹ̀ wọ́n wò. 5 OLUWA ń yẹ àwọn olódodo, ati eniyan burúkú wò, ṣugbọn tọkàntọkàn ni ó kórìíra àwọn tí ó fẹ́ràn ìwà ipá. 6 Yóo rọ̀jò ẹ̀yinná ati imí ọjọ́ gbígbóná sórí àwọn eniyan burúkú; ìjì gbígbóná ni yóo sì jẹ́ ìpín wọn. 7 Nítorí olódodo ni OLUWA, ó sì fẹ́ràn òdodo; àwọn olóòótọ́ ni yóo rí ojú rẹ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria