O. Daf 108 - Yoruba BibleAdura Ìrànlọ́wọ́ láti Borí Ọ̀tá 1 Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun ọkàn mi dúró ṣinṣin. N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́. Jí, ìwọ ọkàn mi! 2 Ẹ jí ẹ̀yin ohun èlò ìkọrin ati hapu! Èmi fúnra mi náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, 3 OLUWA, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwọn eniyan, n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. 4 Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ, òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. 5 Kí á gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, Ọlọrun, kí ògo rẹ sì kárí gbogbo ayé. 6 Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là, fi ọwọ́ agbára rẹ gbà wá, kí o sì dá mi lóhùn. 7 Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀, ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu, n óo sì pín àfonífojì Sukotu. 8 Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase. Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi, Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi. 9 Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé, n óo sì hó ìhó ìṣẹ́gun lórí Filistia.” 10 Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà? Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu? 11 Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀? Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa lọ sójú ogun mọ́. 12 Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa, nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan. 13 Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọ́run, a óo ṣe akin; nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria