Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 104 - Yoruba Bible


Yíyin Ẹlẹ́dàá

1 Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, OLUWA, Ọlọrun mi, ó tóbi pupọ, ọlá ati iyì ni ó wọ̀ bí ẹ̀wù.

2 Ó fi ìmọ́lẹ̀ bora bí aṣọ, ó ta ojú ọ̀run bí ẹni taṣọ.

3 Ìwọ tí o tẹ́ àjà ibùgbé rẹ sórí omi, tí o fi ìkùukùu ṣe kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, tí o sì ń lọ geere lórí afẹ́fẹ́.

4 Ìwọ tí o fi ẹ̀fúùfù ṣe iranṣẹ, tí o sì fi iná ati ahọ́n iná ṣe òjíṣẹ́ rẹ.

5 Ìwọ tí o gbé ayé kalẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, tí kò sì le yẹ̀ laelae.

6 O fi ibú omi bò ó bí aṣọ, omi sì borí àwọn òkè ńlá.

7 Nígbà tí o bá wọn wí, wọ́n sá, nígbà tí o sán ààrá, wọ́n sá sẹ́yìn.

8 Wọ́n ṣàn kọjá lórí òkè lọ sí inú àfonífojì, sí ibi tí o yàn fún wọn.

9 O ti pa ààlà tí wọn kò gbọdọ̀ kọjá, kí wọn má baà tún bo ayé mọ́lẹ̀ mọ́.

10 Ìwọ ni o mú kí àwọn orísun máa tú omi jáde ní àfonífojì; omi wọn sì ń ṣàn láàrin àwọn òkè.

11 Ninu omi wọn ni gbogbo ẹranko tí ń mu, ibẹ̀ sì ni àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń rẹ òùngbẹ.

12 Lẹ́bàá orísun wọnyi ni àwọn ẹyẹ ń gbé, wọ́n sì ń kọrin lórí igi.

13 Láti ibùgbé rẹ lókè ni o tí ń bomi rin àwọn òkè ńlá. Ilẹ̀ sì mu àmutẹ́rùn nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

14 Ó ń mú kí koríko dàgbà fún àwọn ẹran láti jẹ, ati ohun ọ̀gbìn fún ìlò eniyan, kí ó lè máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀;

15 ati ọtí waini tí ń mú inú eniyan dùn, ati epo tí ń mú ojú eniyan dán, ati oúnjẹ tí ń fún ara lókun.

16 Àwọn igi OLUWA ń mu omi ní àmutẹ́rùn, àní àwọn igi kedari Lẹbanoni tí ó gbìn.

17 Lórí wọn ni àwọn ẹyẹ ń tẹ́ ìtẹ́ wọn sí, àkọ̀ sì ń kọ́ ilé rẹ̀ sórí igi firi.

18 Òkè gíga ni ilé ewúrẹ́ igbó, abẹ́ àpáta sì ni ibùgbé ehoro.

19 O dá òṣùpá láti máa sàmì àkókò, oòrùn sì mọ àkókò wíwọ̀ rẹ̀.

20 O mú kí òkùnkùn ṣú, alẹ́ sì lẹ́, gbogbo ẹranko ìgbẹ́ sì ń jẹ kiri.

21 Àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun ń bú fún ìjẹ, wọ́n ń wo ojú Ọlọrun fún oúnjẹ.

22 Nígbà tí oòrùn bá là, wọn á wọ́ lọ; wọn á lọ dùbúlẹ̀ sinu ihò wọn.

23 Ọmọ eniyan á sì jáde lọ síbi iṣẹ́ rẹ̀, á lọ síbi làálàá rẹ̀ títí di àṣáálẹ́.

24 OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ! Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn. Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ.

25 Ẹ wo òkun bí ó ti tóbi tí ó sì fẹ̀, ó kún fún ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá, nǹkan abẹ̀mí kéékèèké ati ńláńlá.

26 Ibẹ̀ ni ọkọ̀ ojú omi ń gbà lọ, ati Lefiatani tí o dá láti máa ṣeré ninu òkun.

27 Ojú rẹ ni gbogbo wọn ń wò, fún ìpèsè oúnjẹ ní àkókò.

28 Nígbà tí o bá fún wọn, wọn á kó o jọ, nígbà tí o bá la ọwọ́, wọn á jẹ ohun dáradára ní àjẹyó.

29 Bí o bá fojú pamọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n, bí o bá gba ẹ̀mí wọn, wọn á kú, wọn á sì pada di erùpẹ̀.

30 Nígbà tí o rán ẹ̀mí rẹ jáde, wọ́n di ẹ̀dá alààyè, o sì sọ orí ilẹ̀ di ọ̀tun.

31 Kí ògo OLUWA máa wà títí lae, kí OLUWA máa yọ̀ ninu iṣẹ́ rẹ̀.

32 Ẹni tí ó wo ilẹ̀, tí ilẹ̀ mì tìtì, tí ó fọwọ́ kan òkè, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ èéfín.

33 N óo kọrin ìyìn sí OLUWA níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè. N óo máa kọrin ìyìn sí Ọlọrun mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀mí mi bá ń bẹ.

34 Kí àṣàrò ọkàn mi kí ó dùn mọ́ ọn ninu nítorí mo láyọ̀ ninu OLUWA.

35 Kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ parẹ́ lórí ilẹ̀ ayé, kí àwọn eniyan burúkú má sí mọ́. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi! Yin OLUWA!

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan