O. Daf 103 - Yoruba BibleÌfẹ́ Ọlọrun 1 Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, fi tinútinú yin orúkọ rẹ̀ mímọ́. 2 Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, má sì ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀, 3 ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn; 4 ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn, tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé. 5 Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn, tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì. 6 OLUWA a máa dáni láre a sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo fún gbogbo àwọn tí a ni lára. 7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ han Mose, ó sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ han àwọn ọmọ Israẹli. 8 Aláàánú ati olóore ni OLUWA, kì í tètè bínú, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀. 9 Kì í fi ìgbà gbogbo báni wí, bẹ́ẹ̀ ni ibinu rẹ̀ kì í pẹ́ títí ayé. 10 Kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa, bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa bí àìdára wa. 11 Nítorí bí ọ̀run ti jìnnà sí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ṣe tóbi tó sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. 12 Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó mú ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa. 13 Bí baba ti máa ń ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA máa ń ṣàánú àwọn tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀. 14 Nítorí ó mọ ẹ̀dá wa; ó ranti pé erùpẹ̀ ni wá. 15 Ọjọ́ ayé ọmọ eniyan dàbí ti koríko, eniyan a sì máa gbilẹ̀ bí òdòdó inú igbó; 16 ṣugbọn bí afẹ́fẹ́ bá ti fẹ́ kọjá lórí rẹ̀, á rẹ̀ dànù, ààyè rẹ̀ kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́. 17 Ṣugbọn títí ayé ni ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀, sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, òdodo rẹ̀ wà lára arọmọdọmọ wọn. 18 Ó wà lára àwọn tí ó ń pa majẹmu rẹ̀ mọ́, tí wọn sì ń ranti láti pa òfin rẹ̀ mọ́. 19 OLUWA ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run, ó sì jọba lórí ohun gbogbo. 20 Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin angẹli rẹ̀, ẹ̀yin alágbára tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, tí ẹ sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. 21 Ẹ yin OLUWA gbogbo ẹ̀yin ọmọ ogun rẹ̀, ẹ̀yin iranṣẹ rẹ̀, tí ẹ̀ ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. 22 Ẹ yin OLUWA, gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, níbi gbogbo ninu ìjọba rẹ̀. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria