O. Daf 100 - Yoruba BibleOrin Ìyìn 1 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA, gbogbo ilẹ̀ ayé. 2 Ẹ fi ayọ̀ sin OLUWA. Ẹ wá siwaju rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀. 3 Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun, òun ló dá wa, òun ló ni wá; àwa ni eniyan rẹ̀, àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀. 4 Ẹ wọ ẹnubodè rẹ̀ tẹ̀yin tọpẹ́, kí ẹ sì wọ inú àgbàlá rẹ̀ tẹ̀yin tìyìn. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa yin orúkọ rẹ̀. 5 Nítorí OLUWA ṣeun; ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae, òtítọ́ rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria