O. Daf 1 - Yoruba BibleÌWÉ ORIN KINNI (Orin Dafidi 1–41) Ayọ̀ Tòótọ́ 1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà tí kò gba ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn, tí kò sì bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́. 2 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA, a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru. 3 Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń so ní àkókò tí ó yẹ, tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere. 4 Àwọn eniyan burúkú kò rí bẹ́ẹ̀, ṣugbọn wọ́n dàbí fùlùfúlù tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ. 5 Nítorí náà àwọn eniyan burúkú kò ní rí ìdáláre, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní le wà ní àwùjọ àwọn olódodo. 6 Nítorí OLUWA ń dáàbò bo àwọn olódodo, ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria