Nahumu 2 - Yoruba BibleÌṣubú Ninefe 1 Atúniká ti gbógun tì ọ́, ìwọ Ninefe. Yan eniyan ṣọ́ ibi ààbò; máa ṣọ́nà, di àmùrè rẹ, kí o sì múra ogun. 2 (Nítorí OLUWA ti ṣetán láti dá ògo Jakọbu pada bí ògo Israẹli, nítorí àwọn tí wọn ń kóni lẹ́rú ti kó wọn, wọ́n sì ti ba àwọn ẹ̀ka wọn jẹ́.) 3 Pupa ni asà àwọn akọni rẹ̀, ẹ̀wù pupa ni àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ̀ Kẹ̀kẹ́ ogun wọn ń kọ mànà bí ọwọ́ iná; nígbà tí wọ́n tò wọ́n jọ, àwọn ẹṣin wọn ń yan. 4 Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń dà wọ ìgboro pẹlu ariwo, wọ́n ń sáré sókè sódò ní gbàgede; wọ́n mọ́lẹ̀ yòò bí iná ìtùfù, wọ́n ń kọ mànà bí mànàmáná. 5 Ó pe àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jọ, wọ́n sì ń fẹsẹ̀ kọ bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n yára lọ sí ibi odi, wọ́n sì fi asà dira ogun. 6 Àwọn ìlẹ̀kùn odò ṣí sílẹ̀, ìdàrúdàpọ̀ wà láàfin. 7 A tú ayaba sí ìhòòhò, a sì mú un lọ sí ìgbèkùn, àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ń dárò rẹ̀, wọ́n káwọ́ lérí, wọ́n ń rin bí oriri. 8 Ìlú Ninefe dàbí adágún odò tí omi rẹ̀ ti ṣàn lọ. Wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ dúró! Ẹ dúró!” Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yíjú pada. 9 Ẹ kó fadaka, ẹ kó wúrà! Ìlú náà kún fún ìṣúra, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye. 10 A ti pa Ninefe run! Ó ti dahoro! Ọkàn àwọn eniyan ti dàrú, orúnkún wọn ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, ìrora dé bá ọpọlọpọ, gbogbo ojú wọn sì rẹ̀wẹ̀sì. 11 Níbo ni ìlú tí ó dàbí ihò àwọn kinniun wà? Tí ó rí bí ibùgbé àwọn ọ̀dọ́ kinniun? Ibi tí kinniun ń gbé oúnjẹ rẹ̀ lọ, tí àwọn ọmọ rẹ̀ wà, tí kò sí ẹni tí ó lè dà wọ́n láàmú? 12 Akọ kinniun a máa fa ẹran ya fún àwọn ọmọ rẹ̀, a sì máa lọ́ ẹran lọ́rùn pa fún àwọn abo rẹ̀; a máa kó ẹran tí ó bá pa ati èyí tí ó fàya sinu ihò rẹ̀. 13 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Mo ti dójú lé ọ. N óo dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, n óo sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun rẹ. Gbogbo ohun tí o ti gbà lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn ni n óo gbà pada lọ́wọ́ rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn àwọn iranṣẹ rẹ mọ́.” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria