Matiu 16 - Yoruba BibleÀwọn Juu ń Fẹ́ Àmì (Mak 8:11-13; Luk 12:54-56) 1 Àwọn Farisi ati àwọn Sadusi wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n ń dán an wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run han àwọn. 2 Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ọjọ́ bá rọ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ dára, nítorí ojú ọ̀run pupa.’ 3 Ní òwúrọ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ìjì yóo jà lónìí nítorí pé ojú ọ̀run pupa, ó sì ṣú.’ Ẹ mọ ohun tí àmì ojú ọ̀run jẹ́, ṣugbọn ẹ kò mọ àwọn àmì àkókò yìí. 4 Ìran burúkú ati oníbọkúbọ ń wá àmì; ṣugbọn a kò ní fi àmì kan fún un, àfi àmì Jona.” Ó bá fi wọ́n sílẹ̀ ó sì bá tirẹ̀ lọ. Ìwúkàrà Àwọn Farisi ati Àwọn Sadusi (Mak 8:14-21) 5 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rékọjá sí òdìkejì òkun, wọ́n gbàgbé láti mú oúnjẹ lọ́wọ́. 6 Jesu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe gáfárà fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati àwọn Sadusi.” 7 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wí láàrin ara wọn pé, “Nítorí a kò mú oúnjẹ lọ́wọ́ wá ni ó ṣe sọ bẹ́ẹ̀.” 8 Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń sọ láàrin ara yín nípa oúnjẹ tí ẹ kò ní, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré? 9 Òye kò ì tíì ye yín sibẹ? Ẹ kò ranti burẹdi marun-un tí mo fi bọ́ ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) eniyan ati iye agbọ̀n àjẹkù tí ẹ kó jọ? 10 Ti burẹdi meje ńkọ́, tí mo fi bọ́ ẹgbaaji (4,000) eniyan ati iye apẹ̀rẹ̀ àjẹkù tí ẹ kó jọ? 11 Kí ló dé tí kò fi ye yín pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ oúnjẹ ni mò ń sọ? Ẹ ṣe gáfárà fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati Sadusi.” 12 Nígbà náà ni ó wá yé wọn pé kì í ṣe ti ìwúkàrà tí à ń fi sinu burẹdi ni ó ń sọ, ti ẹ̀kọ́ àwọn Farisi ati Sadusi ni ó ń sọ. Peteru Jẹ́wọ́ Ẹni tí Jesu Í Ṣe (Mak 8:27-30; Luk 9:18-21) 13 Nígbà tí Jesu dé agbègbè ìlú Kesaria ti Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn eniyan rò pé Ọmọ-Eniyan jẹ́?” 14 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ní Johanu Onítẹ̀bọmi ni. Àwọn mìíràn ní Elija ni. Àwọn mìíràn tún ní Jeremaya ni tabi ọ̀kan ninu àwọn wolii.” 15 Ó wá bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ńkọ́? Ta ni ẹ rò pé mo jẹ́?” 16 Simoni Peteru dá a lóhùn pé, “Ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun Alààyè.” 17 Jesu sọ fún un pé, “O káre, Simoni, ọmọ Jona, nítorí kì í ṣe eniyan ni ó fi èyí hàn ọ́ bíkòṣe Baba mi tí ń bẹ lọ́run. 18 Mo sọ fún ọ pé: Peteru ni ọ́, ní orí àpáta yìí ni n óo kọ́ ìjọ mi lé; agbára ikú kò ní lè ká a. 19 N óo fún ọ ní kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run. Ohunkohun tí o bá dè ní ayé, ó di dídè ní ọ̀run. Ohunkohun tí o bá sì tú ní ayé, ó di títú ní ọ̀run.” 20 Nígbà náà ni Jesu wá pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun ni Mesaya. Jesu Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀ (Mak 8:31-9:1; Luk 9:22-27) 21 Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí máa fihan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé dandan ni kí òun lọ sí Jerusalẹmu, kí òun jìyà pupọ lọ́wọ́ àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin; ati pé kí wọ́n pa òun, ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta a óo jí òun dìde. 22 Ni Peteru bá pè é sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí pé, “Ọlọrun má jẹ́! Oluwa, irú èyí kò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ.” 23 Ṣugbọn Jesu yipada, ó sọ fún Peteru pé, “Kó ara rẹ̀ kúrò níwájú mi, Satani. Ohun ìkọsẹ̀ ni o jẹ́ fún mi, nítorí o kò ro nǹkan ti Ọlọrun, ti eniyan ni ò ń rò.” 24 Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, ó níláti sẹ́ ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 25 Nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi, yóo rí i. 26 Nítorí anfaani wo ni ó ṣe eniyan, tí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀? Tabi kí ni eniyan lè fi dípò ẹ̀mí rẹ̀? 27 Nítorí Ọmọ-Eniyan yóo wá ninu ògo Baba rẹ̀ pẹlu àwọn angẹli rẹ̀, yóo wá fi èrè fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. 28 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn kan wà láàrin àwọn tí ó dúró níhìn-ín, tí kò ní kú títí wọn óo fi rí Ọmọ-Eniyan tí yóo máa bọ̀ wá gẹ́gẹ́ bí Ọba.” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria