Malaki 4 - Yoruba BibleỌjọ́ OLUWA ń bọ̀ 1 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Ọjọ́ náà ń bọ̀ bí iná ìléru, tí àwọn agbéraga ati àwọn oníṣẹ́ ibi yóo jóná bíi koríko gbígbẹ. Ráúráú ni wọn óo jóná. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí! 2 Ṣugbọn ní ti ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù mi, oòrùn òdodo yóo tàn si yín pẹlu ìwòsàn mi, ẹ óo máa yan káàkiri bí ọmọ ẹran tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tú sílẹ̀. 3 Ẹ óo tẹ àwọn eniyan burúkú mọ́lẹ̀, nítorí wọn yóo di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ tí mo bá fi agbára mi hàn. 4 “Ẹ ranti òfin ati ìlànà tí mo ti fún Mose, iranṣẹ mi, fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní orí òkè Horebu. 5 “Ẹ wò ó! N óo rán wolii Elija si yín kí ọjọ́ ńlá OLUWA, tí ó bani lẹ́rù náà tó dé. 6 Yóo yí ọkàn àwọn baba pada sọ́dọ̀ àwọn ọmọ wọn, yóo sì yí ti àwọn ọmọ, pada sọ́dọ̀ àwọn baba wọn; kí n má baà fi ilẹ̀ náà gégùn-ún.” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria