Jona 2 - Yoruba BibleAdura Jona 1 Jona gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ láti inú ẹja náà, 2 ó ní, “Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn, mo ké pè é láti inú isà òkú, ó sì gbóhùn mi. 3 Nítorí pé, ó gbé mi jù sinu ibú, ní ààrin agbami òkun, omi òkun sì bò mí mọ́lẹ̀; ọwọ́ agbára rírú omi òkun rẹ̀ sì ń wọ́ kọjá lórí mi. 4 Nígbà náà ni mo sọ pé, ‘A ti ta mí nù kúrò níwájú rẹ; báwo ni n óo ṣe tún rí tẹmpili mímọ́ rẹ?’ 5 Omi bò mí mọ́lẹ̀, ibú omi yí mi ká, koríko inú omi sì wé mọ́ mi lórí. 6 Mo já sí ibi tí ó jìn jùlọ ninu òkun, àní ibi tí ẹnikẹ́ni kò lọ ní àlọ-bọ̀ rí. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA Ọlọrun mi, o mú ẹ̀mí mi jáde láti inú ibú náà. 7 Nígbà tí ẹ̀mí mi ń bọ́ lọ, mo gbadura sí ìwọ OLUWA, o sì gbọ́ adura mi ninu tẹmpili mímọ́ rẹ. 8 Àwọn tí wọn ń sin àwọn oriṣa lásánlàsàn kọ̀, wọn kò pa ìlérí wọn sí ọ mọ́. 9 Ṣugbọn n óo rúbọ sí ọ pẹlu ohùn ọpẹ́, n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi. Ti OLUWA ni ìgbàlà!” 10 OLUWA bá pàṣẹ fún ẹja tí ó gbé Jona mì, ó sì lọ pọ̀ ọ́ sí èbúté, lórí ilẹ̀ gbígbẹ. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria