Jobu 9 - Yoruba Bible1 Jobu dáhùn pé: 2 “Lóòótọ́, mo mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí, ṣugbọn báwo ni ẹlẹ́ran ara ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun? 3 Bí eniyan tilẹ̀ fẹ́ bá a jiyàn, olúwarẹ̀ kò ní lè dáhùn ẹyọ kan ninu ẹgbẹrun ìbéèrè tí yóo bèèrè. 4 Ọgbọ́n rẹ̀ jinlẹ̀, agbára rẹ̀ sì pọ̀. Ta ló tó ṣe oríkunkun sí i kí ó mú un jẹ? 5 Ẹni tí ó ṣí àwọn òkè nídìí, ninu ibinu rẹ̀; tí wọn kò sì mọ ẹni tí ó bì wọ́n ṣubú. 6 Ó ti ayé kúrò ní ipò rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀ sì wárìrì. 7 Ó pàṣẹ fún oòrùn, oòrùn kò sì yọ; ó sé àwọn ìràwọ̀ mọ́lé; 8 òun nìkan ṣoṣo ni ó dá ojú ọ̀run tẹ́ bí aṣọ, tí ó sì tẹ ìgbì omi òkun mọ́lẹ̀. 9 Ó dá àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run: Beari, Orioni, ati Pileiadesi ati àwọn ìràwọ̀ ìhà gúsù. 10 Ó ṣe àwọn ohun ńlá tí ó kọjá òye ẹ̀dá, ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí kò ní òǹkà. 11 Ó gba ẹ̀gbẹ́ mi kọjá, n kò rí i, ó ń kọjá lọ, n kò sì mọ̀. 12 Wò ó! Ó já àwọn ohun tí ó wù ú gbà, ta ló lè dá a dúró? Ta ló tó bi í pé, ‘Kí ni ò ń ṣe?’ 13 “Ọlọrun kò ní dáwọ́ ibinu rẹ̀ dúró, yóo fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn olùrànlọ́wọ́ Rahabu mọ́lẹ̀. 14 Báwo ni mo ṣe lè bá a rojọ́? Kí ni kí n sọ? 15 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi, sibẹsibẹ n kò lè dá a lóhùn. Ẹ̀bẹ̀ nìkan ni mo lè bẹ̀ fún àánú, lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ẹ̀sùn kàn mí. 16 Bí mo bá pè é pé kó wá gbọ́, tí ó sì dá mi lóhùn, sibẹ n kò lè gbàgbọ́ pé yóo dẹtí sílẹ̀ gbọ́rọ̀ mi. 17 Nítorí pé ó ti fi ìjì tẹ̀ mí mọ́lẹ̀, ó sì sọ egbò mi di pupọ láìnídìí; 18 kò ní jẹ́ kí n mí, ìbànújẹ́ ni ó fi kún ọkàn mi. 19 Bí ó bá ṣe ti pé kí á dán agbára wò ni, agbára rẹ̀ pọ̀ tayọ! Bí ó bá sì jẹ́ pé ti ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́, ta ló lè pè é lẹ́jọ́? 20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́bi, sibẹsibẹ ọ̀rọ̀ ẹnu mi yóo di ẹ̀bi rù mí; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lẹ́ṣẹ̀, sibẹsibẹ yóo fihàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí. 21 N kò lẹ́bi, sibẹ n kò ka ara mi kún, ayé sú mi. 22 Kò sí ìyàtọ̀ lójú rẹ̀, nítorí náà ni mo fi wí pé, ati ẹlẹ́bi ati aláìlẹ́bi ni ó ti parun. 23 Nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀, tí ó já sí ikú òjijì, a máa fi aláìṣẹ̀ ṣe ẹlẹ́yà ninu ìdààmú wọn. 24 A ti fi ayé lé àwọn ẹni ibi lọ́wọ́, ó ti di àwọn adájọ́ rẹ̀ lójú. Bí kì í bá ṣe òun Ọlọrun, ta ló tún tó bẹ́ẹ̀? 25 “Ọjọ́ ayé mi ń sáré lọ tete, kò sí ẹyọ ọjọ́ kan tí ó dára ninu wọn. 26 Wọ́n sáré kọjá lọ bíi koríko ojú omi, bí ẹyẹ idì tí ń fò fẹ̀ẹ̀ lọ bá ohun tí ó fẹ́ pa. 27 Bí mo bá sọ pé kí n gbàgbé ìráhùn mi, kí n sì tújúká; kí n má ronú mọ́; 28 ẹ̀rù ìrora mi á bẹ̀rẹ̀ sí bà mí, nítorí mo mọ̀ pé o kò ní gbà pé n kò dẹ́ṣẹ̀. 29 Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá mi lẹ́bi, kí ni mo tún ń ṣe wahala lásán fún? 30 Ọṣẹ yòówù tí mo lè fi wẹ̀, kódà kí n fi omi yìnyín fọ ọwọ́, 31 sibẹ o óo tì mí sinu kòtò ìdọ̀tí. Kódà n óo di ohun ìríra sí aṣọ ara mi. 32 Ọlọrun kì í ṣe eniyan bíì mi, tí mo fi lè fún un lésì, tí a fi lè jọ rojọ́ ní ilé ẹjọ́. 33 Kò sí ẹnìkẹta láàrin àwa mejeeji, tí ó lè dá wa lẹ́kun. 34 Kí ó sọ pàṣán rẹ̀ sílẹ̀, kí ó má nà mí mọ́! Kí ìbẹ̀rù rẹ̀ má sì pá mi láyà mọ́! 35 Kí n baà le sọ̀rọ̀ láìbẹ̀rù, nítorí mo mọ inú ara mi. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria