Jobu 6 - Yoruba Bible1 Jobu bá dáhùn pé, 2 “Bí ó bá ṣeéṣe láti wọn ìbànújẹ́ mi, tí a bá sì le gbé ìdààmú mi lé orí ìwọ̀n, 3 ìbá wúwo ju yanrìn etí òkun lọ. Ìdí nìyí tí mo fi ń fi ìtara sọ̀rọ̀. 4 Ọfà Olodumare wọ̀ mí lára, oró rẹ̀ sì mú mi. Ọlọrun kó ìpayà bá mi. 5 Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó a máa ké tí ó bá rí koríko jẹ? Àbí mààlúù a máa dún tí ó bá ń wo oúnjẹ rẹ̀ nílẹ̀? 6 Ǹjẹ́ ohun tí kò dùn ṣe é jẹ láì fi iyọ̀ sí i? Tabi, adùn wo ní ń bẹ ninu funfun ẹyin? 7 Irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ kì í wù mí í jẹ, Ìríra ni jíjẹ rẹ̀ jẹ́ fún mi. 8 “Ìbá ti dára tó, kí Ọlọrun mú ìbéèrè mi ṣẹ, kí ó fún mi ní ohun tí ọkàn mi ń fẹ́. 9 Àní, kí ó wó mi mọ́lẹ̀, kí ó mú mi, kí ó pa mí dànù. 10 Yóo jẹ́ ìtùnú fún mi; n óo sì láyọ̀ ninu ọpọlọpọ ìrora, nítorí pé n kò sẹ́ ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́. 11 Agbára wo ni mo ní, tí mo fi lè tún máa wà láàyè? Kí sì ni ìrètí mi, tí n óo fi tún máa ní sùúrù? 12 Agbára mi ha rí bí ti òkúta bí? Àbí ẹran ara mi jẹ́ idẹ? 13 Nítòótọ́, n kò ní agbára mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní olùrànlọ́wọ́. 14 “Ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣàánú ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò ní ìbẹ̀rù Olodumare. 15 Ṣugbọn, ẹ̀yin arakunrin mi, ẹlẹ́tàn ni yín, bíi odò àgbàrá tí ó yára kún, tí ó sì tún yára gbẹ, 16 tí yìnyín bo odò náà tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣókùnkùn, tí yìnyín ńláńlá sì farapamọ́ sibẹ, 17 ṣugbọn ní àkókò ooru, wọn a yọ́, bí ilẹ̀ bá ti gbóná, wọn a sì gbẹ. 18 Àwọn oníṣòwò tí ń lo ràkúnmí yà kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n ń wá omi kiri wọ́n kiri títí wọ́n fi ṣègbé ninu aṣálẹ̀. 19 Àwọn oníṣòwò Temani ń wò rá rà rá, àwọn ọ̀wọ́ èrò Ṣeba sì dúró pẹlu ìrètí. 20 Ìrètí wọn di òfo nítorí wọ́n ní ìdánilójú. Wọ́n dé ibi tí odò wà tẹ́lẹ̀, ṣugbọn òfo ni wọ́n bá. 21 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ rí sí mi nisinsinyii. Ẹ rí ìdààmú mi, ẹ̀rù bà yín. 22 Ǹjẹ́ mo tọrọ ẹ̀bùn lọ́wọ́ yín? Tabi mo bẹ̀ yín pé kí ẹ mú ninu owó yín, kí ẹ fi san àbẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí mi? 23 Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín pé kí ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá; tabi pé kí ẹ rà mí pada kúrò lọ́wọ́ aninilára? 24 “Ó dára, mo gbọ́, ẹ wá kọ́ mi, ẹ ṣàlàyé ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣẹ̀ fún mi; n óo sì dákẹ́ n óo tẹ́tí sílẹ̀. 25 Lóòótọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ ní agbára, ṣugbọn kí ni ẹ̀ ń bá mi wí lé lórí. 26 Ẹ rò pé mò ń fi ọ̀rọ̀ ṣòfò lásán ni? Kí ni ẹ̀ ń dásí ọ̀rọ̀ èmi onírora sí? 27 Ẹ tilẹ̀ lè ṣẹ́ gègé lórí ọmọ òrukàn, ẹ sì lè díye lé ọ̀rẹ́ yín. 28 “Ẹ gbọ́, ẹ wò mí dáradára, nítorí n kò ní purọ́ níwájú yín. 29 Mo bẹ̀ yín, ẹ dúró bẹ́ẹ̀, kí ẹ má baà ṣẹ̀. Ẹ dúró bẹ́ẹ̀, nítorí n kò lẹ́bi. 30 Ṣé ẹ rò pé mò ń parọ́ ni? Àbí n kò mọ nǹkan burúkú yàtọ̀? |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria