Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Jobu 4 - Yoruba Bible


Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Kinni
(4:1–14:22)

1 Nígbà náà ni Elifasi, ará Temani, dá Jobu lóhùn, ó ní:

2 “Bí eniyan bá bá ọ sọ̀rọ̀, ṣé kò ní bí ọ ninu? Àbí eniyan ha lè dákẹ́ bí?

3 O ti kọ́ ọpọlọpọ eniyan, o ti fún aláìlera lókun.

4 O ti fi ọ̀rọ̀ gbé àwọn tí wọn ń ṣubú ró, ọ̀rọ̀ rẹ ti fún orúnkún tí ń yẹ̀ lọ lágbára.

5 Ṣugbọn nisinsinyii tí ọ̀rọ̀ kàn ọ́, o kò ní sùúrù; Ó dé bá ọ, ìdààmú bá ọ.

6 Ṣé ìbẹ̀rù Ọlọrun kò tó ìgboyà fún ọ? Àbí ìwà òdodo rẹ kò fún ọ ní ìrètí?

7 “Ìwọ náà ronú wò, ṣé aláìṣẹ̀ kan ṣègbé rí? Tabi olódodo kan parun rí?

8 Bí èmi ti rí i sí ni pé, ẹni tí ó kọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ebè, tí ó sì gbin wahala, yóo kórè ìyọnu.

9 Èémí Ọlọrun níí pa wọ́n run, ninu ibinu rẹ̀, wọ́n a sì ṣègbé.

10 Ọlọrun fi òpin sí igbe kinniun, ati bíbú tí kinniun ń bú ramúramù, ó sì wọ́ àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun léyín.

11 Kinniun alágbára a máa kú, nítorí àìrí ẹran pa jẹ, àwọn ọmọ abo kinniun a sì fọ́nká.

12 “Nisinsinyii wọ́n fọ̀rọ̀ kan tó mi létí mo gbọ́ wúyẹ́-wúyẹ́ rẹ̀.

13 Ninu ìran lóru, nígbà tí àwọn eniyan sùn fọnfọn,

14 ìbẹ̀rùbojo mú mi, gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì.

15 Ẹ̀mí kan kọjá fìrí níwájú mi, gbogbo irun ara mi sì dìde.

16 Ó dúró jẹ́ẹ́, ṣugbọn n kò mọ̀ bí ó ti rí. Mo ṣá rí kinní kan tí ó dúró; gbogbo nǹkan parọ́rọ́, nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn kan tí ó wí pé,

17 ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun? Tabi kí eniyan jẹ́ mímọ́ níwájú Ẹlẹ́dàá rẹ̀?

18 Nígbà tí ó jẹ́ pé, Ọlọrun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn iranṣẹ rẹ̀, a sì máa bá àṣìṣe lọ́wọ́ àwọn angẹli rẹ̀;

19 mélòó mélòó wá ni eniyan tí a fi amọ̀ mọ, tí ìpìlẹ̀ wọn jẹ́ erùpẹ̀, tí a lè pa bíi kòkòrò lásánlàsàn.

20 Eniyan lè wà láàyè ní òwúrọ̀ kí ó kú kí ó tó di ọjọ́ alẹ́, wọn a parun títí lae láìsí ẹni tí yóo bìkítà.

21 Bí a bá gba gbogbo ohun tí wọ́n fẹ̀mí tẹ̀, ṣé wọn kò ní kú bí aláìgbọ́n?’

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan