Jobu 26 - Yoruba Bible1 Jobu bá dáhùn pé, 2 “Ìrànlọ́wọ́ wo ni ẹ ti ṣe fún àwọn tí wọn kò lágbára? Aláìlera wo ni ẹ ti gbàlà? 3 Ìmọ̀ràn wo ni ẹ ti fún àwọn aláìgbọ́n? Irú òye wo ni ẹ fihàn wọ́n? 4 Ta ló ń kọ yín ni ohun tí ẹ̀ ń sọ wọnyi? Irú ẹ̀mí wo sì ní ń gba ẹnu yín sọ̀rọ̀? 5 “Àwọn òkú wárìrì nísàlẹ̀. Omi ati àwọn olùgbé inú rẹ̀ pẹlu ń gbọ̀n rìrì. 6 Kedere ni isà òkú rí níwájú Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni ìparun kò farasin. 7 Ó na ìhà àríwá sórí òfuurufú, ó sì so ayé rọ̀ sí òfuurufú. 8 Ó di omi papọ̀ ninu ìkùukùu rẹ̀ tí ó nípọn, sibẹ ìkùukùu kò fà ya. 9 Ó dí ojú òṣùpá, ó sì fi ìkùukùu bò ó. 10 Ó ṣe òbìrìkítí kan sórí omi, ó fi ṣe ààlà láàrin òkùnkùn ati ìmọ́lẹ̀. 11 Àwọn òpó ọ̀run mì tìtì, wọ́n sì wárìrì nítorí ìbáwí rẹ̀. 12 Nípa agbára rẹ̀, ó mú kí òkun parọ́rọ́, nípa ìmọ̀ rẹ̀, ó pa Rahabu. 13 Ó fi afẹ́fẹ́ ṣe ojú ọ̀run lọ́ṣọ̀ọ́; ọwọ́ ló fi pa ejò tí ń fò. 14 Ṣugbọn kékeré nìyí ninu agbára rẹ̀, díẹ̀ ni a tíì gbọ́ nípa iṣẹ́ rẹ̀! Nítorí náà ta ló lè mọ títóbi agbára rẹ̀?” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria