Jobu 25 - Yoruba Bible1 Bilidadi ará Ṣuha bá dáhùn pé, 2 “Ọlọrun ni ọba, òun ló sì tó bẹ̀rù, ó ń ṣe àkóso alaafia lọ́run. 3 Ta ló lè ka àwọn ọmọ ogun rẹ̀? Ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí? 4 Báwo wá ni eniyan ṣe lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun? Báwo ni ẹni tí obinrin bí ṣe lè jẹ́ ẹni mímọ́? 5 Wò ó, òṣùpá pàápàá kò mọ́lẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìràwọ̀ kò mọ́ tó lójú rẹ̀; 6 kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti eniyan tí ó dàbí ìdin, tabi ọmọ eniyan tí ó dàbí ekòló lásánlàsàn!” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria