Jobu 23 - Yoruba Bible1 Nígbà náà ni Jobu dáhùn pé, 2 “Lónìí, ìráhùn mi tún kún fún ẹ̀dùn, ọwọ́ Ọlọrun ń le lára mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń kérora. 3 Áà! Ìbá jẹ́ pé mo mọ ibi tí mo ti lè rí i ni, ǹ bá lọ siwaju ìtẹ́ rẹ̀! 4 Ǹ bá ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ̀, gbogbo ẹnu ni ǹ bá fi ṣàròyé. 5 Ǹ bá gbọ́ èsì tí yóo fún mi, ati ọ̀rọ̀ tí yóo sọ fún mi. 6 Ṣé yóo gbéjà kò mí pẹlu agbára ńlá rẹ̀? Rárá o, yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi. 7 Ibẹ̀ ni olódodo yóo ti lè sọ ti ẹnu rẹ̀, yóo sì dá mi sílẹ̀ títí lae. 8 “Wò ó! Mo lọ siwaju, kò sí níbẹ̀, mo pada sẹ́yìn, n kò gbúròó rẹ̀. 9 Mo wo apá ọ̀tún, n kò rí i, mo wo apá òsì, kò sí níbẹ̀. 10 Ṣugbọn ó mọ gbogbo ọ̀nà mi, ìgbà tí ó bá dán mi wò tán, n óo yege bíi wúrà. 11 Mò ń tẹ̀lé e lẹ́yìn, mo súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, n kò tíì yipada kúrò ní ọ̀nà rẹ̀. 12 N kò tíì yapa kúrò ninu àṣẹ tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde, mò ń pa wọ́n mọ́ ninu ọkàn mi. 13 “Ṣugbọn Ọlọrun kìí yipada, kò sí ẹni tí ó lè yí i lọ́kàn pada. Ohun tí ó bá fẹ́ gan-an ni yóo ṣe. 14 Yóo ṣe ohun tí ó ti pinnu láti ṣe fún mi ní àṣeyọrí, ati ọpọlọpọ nǹkan bẹ́ẹ̀ yòókù tí ó tún ní lọ́kàn láti ṣe fún mi. 15 Ìdí nìyí tí ẹ̀rù fi bà mí níwájú rẹ̀, tí mo bá ro nǹkan wọnyi, jìnnìjìnnì rẹ̀ a bò mí. 16 Ọlọrun ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi, Olodumare ti dẹ́rùbà mí. 17 Nítorí pé òkùnkùn yí mi ká, òkùnkùn biribiri sì ṣú bò mí lójú. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria