Jobu 22 - Yoruba BibleÌFỌ̀RỌ̀WÉRỌ̀ KẸTA (22:1–27:23) 1 Elifasi ará Temani bá dáhùn pé, 2 “Ǹjẹ́ eniyan lè wúlò fún Ọlọrun? Nítòótọ́, bí eniyan tilẹ̀ jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ara rẹ̀ ni ó wúlò fún. 3 Ǹjẹ́ jíjẹ́ olódodo rẹ̀ ṣe ohun rere kan fún Olodumare, tabi kí ni èrè rẹ̀ bí ó bá jẹ́ ẹni pípé? 4 Ṣé nítorí pé o bẹ̀rù rẹ̀ ni ó ṣe bá ọ wí, tí ó sì ń dá ọ lẹ́jọ́? 5 Ṣebí ìwà ibi rẹ ló pọ̀; tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lópin? 6 O gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ àwọn arakunrin rẹ láìnídìí, O bọ́ wọn sí ìhòòhò goloto. 7 O kò fún aláàárẹ̀ ní omi mu, o kọ̀ láti fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ. 8 Ẹni tí ó lágbára gba ilẹ̀, ẹni tí ó lọ́lá sì ń gbé inú rẹ̀. 9 O lé àwọn opó jáde lọ́wọ́ òfo, o sì ṣẹ́ aláìní baba lápá. 10 Nítorí náà ni okùn dídẹ fi yí ọ ká, tí jìnnìjìnnì sì bò ọ́ lójijì. 11 Ìmọ́lẹ̀ rẹ ti di òkùnkùn, o kò ríran, ìgbì omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀. 12 “Ṣebí Ọlọrun wà lókè ọ̀run Ó ń wo àwọn ìràwọ̀ nísàlẹ̀ àní àwọn tí wọ́n ga jùlọ, bí ó ti wù kí wọ́n ga tó! 13 Sibẹsibẹ ò ń bèèrè pé, ‘Kí ni Ọlọrun mọ̀?’ Ṣé ó lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn biribiri? 14 Ìkùukùu tí ó nípọn yí i ká, tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè ríran, ó sì ń rìn ní òfuurufú ojú ọ̀run. 15 “Ṣé ọ̀nà àtijọ́ ni ìwọ óo máa tẹ̀lé; ọ̀nà tí àwọn ẹni ibi rìn? 16 A gbá wọn dànù, kí àkókò wọn tó tó, a ti gbá ìpìlẹ̀ wọn lọ. 17 Wọ́n sọ fún Ọlọrun pé, ‘Fi wá sílẹ̀, kí ni ìwọ Olodumare lè fi wá ṣe?’ 18 Sibẹsibẹ ó fi ìṣúra dáradára kún ilé wọn– ṣugbọn ìmọ̀ràn ẹni ibi jìnnà sí mi. 19 Àwọn olódodo rí i, inú wọn dùn, àwọn aláìlẹ́bi fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, 20 wọ́n ń wí pé, ‘Dájúdájú, àwọn ọ̀tá wa ti parun, iná sì ti jó gbogbo ohun tí wọ́n fi sílẹ̀.’ 21 “Nisinsinyii gba ti Ọlọrun, kí o sì wà ní alaafia; kí ó lè dára fún ọ. 22 Gba ìtọ́ni rẹ̀, kí o sì kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ lékàn. 23 Bí o bá yipada sí Olodumare, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀, tí o bá mú ìwà aiṣododo kúrò ní ibùgbé rẹ, 24 bí o bá ri wúrà mọ́ inú erùpẹ̀, tí o fi wúrà Ofiri sí ààrin àwọn òkúta ìsàlẹ̀ odò, 25 bí Olodumare bá sì jẹ́ wúrà rẹ, ati fadaka olówó iyebíye rẹ, 26 nígbà náà ni o óo láyọ̀ ninu Olodumare, o óo sì lè dúró níwájú Ọlọrun. 27 Nígbà náà, o óo gbadura sí i, yóo sì gbọ́, o óo sì san ẹ̀jẹ́ rẹ. 28 Ohunkohun tí o bá pinnu láti mú ṣe, yóo ṣeéṣe fún ọ, ìmọ́lẹ̀ yóo sì tàn sí ọ̀nà rẹ. 29 Nítorí Ọlọrun a máa rẹ onigbeeraga sílẹ̀, a sì máa gba onírẹ̀lẹ̀. 30 A máa gba àwọn aláìṣẹ̀, yóo sì gbà ọ́ là, nípa ìwà mímọ́ rẹ.” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria