Jobu 14 - Yoruba Bible1 “Ẹnikẹ́ni tí obinrin bá bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ìpọ́njú. 2 Yóo kọ́ yọ bí òdòdó, lẹ́yìn náà yóo sì rẹ̀ dànù. Yóo kọjá lọ bí òjìji, kò sì ní sí mọ́. 3 Ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni o dojú kọ, tí ò ń bá ṣe ẹjọ́? 4 Ta ló lè mú ohun mímọ́ jáde láti inú ohun tí kò mọ́? Kò sí ẹni náà. 5 Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá ọjọ́ fún un, tí o mọ iye oṣù rẹ̀, tí o sì ti pa ààlà tí kò lè rékọjá. 6 Mú ojú rẹ kúrò lára rẹ̀, kí ó lè sinmi, kí ó sì lè gbádùn ọjọ́ ayé rẹ̀ bí alágbàṣe. 7 “Nítorí pé ìrètí ń bẹ fún igi tí wọn gé, yóo tún pada rúwé, ẹ̀ka rẹ̀ kò sì ní ṣe aláìsọ. 8 Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ògbólógbòó ninu ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ sì kú, 9 bí ó bá ti gbóòórùn omi, yóo sọ, yóo sì yọ ẹ̀ka bí ọ̀dọ́ irúgbìn. 10 Ṣugbọn bí eniyan bá kú, a óo tẹ́ ẹ sinu ibojì, bí ó bá ti gbẹ́mìí mì, ó di aláìsí. 11 Bí adágún omi tíí gbẹ, ati bí odò tíí ṣàn lọ, tí sìí gbẹ, 12 bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe é sùn, tí kì í sìí jí mọ́, títí tí ọ̀run yóo fi kọjá lọ, kò ní jí, tabi kí ó tilẹ̀ rúnra láti ojú oorun. 13 Ìbá sàn kí o fi mí pamọ́ sinu ibojì, kí o pa mí mọ́ títí inú rẹ yóo fi rọ̀, ò bá dá àkókò fún mi, kí o sì ranti mi. 14 Bí eniyan bá kú, ǹjẹ́ yóo tún jí mọ́? N óo dúró ní gbogbo ọjọ́ làálàá mi, n óo máa retí, títí ọjọ́ ìdáǹdè mi yóo fi dé. 15 O óo pè mí, n ó sì dá ọ lóhùn, o óo máa ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. 16 Nígbà náà, o óo máa tọ́ ìṣísẹ̀ mi, o kò sì ní ṣọ́ àwọn àṣìṣe mi. 17 O óo di àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi sinu àpò, o óo sì bo àwọn àìdára mi mọ́lẹ̀. 18 “Ṣugbọn òkè ńlá ṣubú, ó sì rún wómúwómú, a sì ṣí àpáta nídìí kúrò ní ipò rẹ̀. 19 Bí omi ṣe é yìnrìn òkúta, tí àgbàrá sì í wọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe sọ ìrètí eniyan di òfo. 20 O ṣẹgun rẹ̀ títí lae, ó sì kọjá lọ, o yí àwọ̀ rẹ̀ pada, o sì mú kí ó lọ. 21 Wọ́n dá àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́lá, ṣugbọn kò mọ̀, a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, sibẹ kò rí i. 22 Ìrora ara rẹ̀ nìkan ló mọ̀, ọ̀fọ̀ ara rẹ̀ nìkan ni ó ń ṣe.” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria