Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Jobu 13 - Yoruba Bible

1 “Gbogbo ìwọ̀nyí ni ojú mi ti rí rí, tí etí mi ti gbọ́, tí ó sì yé mi.

2 Ohun tí ẹ mọ̀ wọnyi, èmi náà mọ̀ ọ́n, ẹ kò sàn jù mí lọ.

3 Ṣugbọn n óo bá Olodumare sọ̀rọ̀, Ọlọrun ni mo sì fẹ́ bá rojọ́.

4 Ẹ̀yin òpùrọ́ ati ẹlẹ́tàn wọnyi, ẹ̀yin oníṣègùn tí ẹ kò lè wonisàn.

5 Ẹ̀ bá jẹ́ pa ẹnu yín mọ́ ni, à bá pè yín ní ọlọ́gbọ́n!

6 Nisinsinyii ẹ gbọ́ èrò ọkàn mi, kí ẹ sì fetísí àròyé mi.

7 Ṣé ẹ óo máa parọ́ ní orúkọ Ọlọrun ni, kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní orúkọ rẹ̀?

8 Ṣé ẹ fẹ́ máa ṣe ojuṣaaju fún Ọlọrun ni? Tabi ẹ fẹ́ jẹ́ agbẹjọ́rò rẹ̀?

9 Ṣé ẹ óo yege bí ó bá dán yín wò? Tabi ẹ lè tan Ọlọrun bí ẹni tan eniyan?

10 Dájúdájú, yóo ba yín wí, bí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju níkọ̀kọ̀.

11 Ògo rẹ̀ yóo dẹ́rùbà yín, jìnnìjìnnì rẹ̀ yóo dà bò yín.

12 Àwọn òwe yín kò wúlò, àwíjàre yín kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

13 Ẹ dákẹ́, kí n ráyè sọ tèmi, kí ohun tí yóo bá dé bá mi dé bá mi.

14 N óo dijú, n óo fi ẹ̀mí ara mi wéwu.

15 Wò ó, yóo pa mí; n kò ní ìrètí; sibẹ n óo wí àwíjàre tèmi níwájú rẹ̀.

16 Èyí ni yóo jẹ́ ìgbàlà mi, nítorí pé ẹni tí kò mọ Ọlọrun, kò ní lè dúró níwájú rẹ̀.

17 Fetí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi, kí o sì gbọ́ mi ní àgbọ́yé.

18 Wò ó, mo ti múra ẹjọ́ mi sílẹ̀; mo sì mọ̀ pé n óo gba ìdáláre.

19 Ta ni yóo wá bá mi rojọ́? Bí ó bá wá, n óo dákẹ́, n óo sì kú.

20 Nǹkan meji péré ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi, n kò sì ní farapamọ́ fún ọ:

21 ká ọwọ́ ibinu rẹ kúrò lára mi, má sì ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì rẹ dà bò mí.

22 Lẹ́yìn náà, sọ̀rọ̀, n óo sì fèsì; tabi kí o jẹ́ kí èmi sọ̀rọ̀, kí o sì fún mi lésì.

23 Báwo ni àìdára ati ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀ tó? Jẹ́ kí n mọ ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati ibi tí mo ti kọjá ààyè mi.

24 Kí ló dé tí o fi fi ara pamọ́ fún mi tí o kà mí kún ọ̀tá rẹ?

25 Ṣé o óo máa dẹ́rùba ewé lásán tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri, tabi o óo máa lépa ìyàngbò gbígbẹ?

26 O ti kọ àkọsílẹ̀ burúkú nípa mi, o mú mi jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi.

27 O kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí mi lẹ́sẹ̀, ò ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi, o sì pa ààlà tí n kò gbọdọ̀ rékọjá.

28 Eniyan ń ṣègbé lọ bí ohun tí ó ń jẹrà, bí aṣọ tí ikán ti mu.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan