Jobu 11 - Yoruba Bible1 Sofari ará Naama dáhùn pé, 2 “Ǹjẹ́ ó dára kí eniyan sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ kalẹ̀ báyìí kí ó má sì ìdáhùn? Àbí, ṣé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ lè mú kí á dá eniyan láre? 3 Ṣé o rò pé ìsọkúsọ rẹ lè pa eniyan lẹ́nu mọ́ ni? Tabi pé bí o bá ń ṣe ẹlẹ́yà ẹnikẹ́ni kò lè dójútì ọ́? 4 Nítorí o sọ pé ẹ̀kọ́ rẹ tọ̀nà, ati pé ẹni mímọ́ ni ọ́ lójú Ọlọrun. 5 Ọlọrun ìbá ya ẹnu rẹ̀, kí ó sọ̀rọ̀ sí ọ. 6 Kì bá jẹ́ fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́, nítorí ìmọ̀ rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ. Mọ̀ dájú pé ìyà tí Ọlọrun fi jẹ ọ́ kò to nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. 7 “Ǹjẹ́ o lè wádìí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa Ọlọrun? Tabi kí o tọpinpin Olodumare? 8 Ó ga ju ọ̀run lọ, kí lo lè ṣe sí i? Ó jìn ju isà òkú lọ, kí lo lè mọ̀ nípa rẹ̀? 9 Ó gùn ju ayé lọ, Ó sì fẹ̀ ju òkun lọ. 10 Tí ó bá ń kọjá lọ, tí ó sì ti eniyan mọ́lé, tí ó pe olúwarẹ̀ lẹ́jọ́, ta ló lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò? 11 Nítorí ó mọ àwọn eniyan lásán, ṣé bí ó bá rí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó má ṣe akiyesi rẹ̀? 12 Ó di ìgbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá bí ọmọ rẹ̀ ní eniyan, kí òmùgọ̀ eniyan tó gbọ́n. 13 “Bí o bá fi ọkàn rẹ sí ohun tí ó tọ́, o óo lè nawọ́ sí i. 14 Bí o bá ń dẹ́ṣẹ̀, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́, má sì ṣe jẹ́ kí ìwà burúkú, wà ní ọwọ́ rẹ. 15 Nígbà náà ni o óo tó lè fi ìgboyà gbójú sókè láìlẹ́bi; o óo wà láìléwu, o kò sì ní bẹ̀rù. 16 O óo gbàgbé àwọn ìyọnu rẹ, nígbà tí o bá sì ranti rẹ̀, yóo dàbí ìkún omi tí ó ti wọ́ lọ. 17 Ayé rẹ yóo mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ; òkùnkùn rẹ yóo sì dàbí òwúrọ̀. 18 Ọkàn rẹ óo balẹ̀, nítorí pé o ní ìrètí, a óo dáàbò bò ọ́, o óo sì sinmi láìséwu. 19 O óo sùn, láìsí ìdágìrì, ọpọlọpọ eniyan ni wọn óo sì máa wá ojurere rẹ. 20 Àwọn ẹni ibi óo pòfo; gbogbo ọ̀nà tí wọ́n lè gbà sá àsálà ni yóo parẹ́ mọ́ wọn lójú, ikú ni yóo sì jẹ́ ìrètí wọn.” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria