Jeremiah 45 - Yoruba BibleÌlérí Ọlọrun fún Baruku 1 Ọ̀rọ̀ tí Jeremaya wolii sọ fún Baruku ọmọ Neraya nìyí, ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya, jọba ní Juda. Baruku ń kọ ohun tí Jeremaya ń sọ sílẹ̀ bí Jeremaya tí ń sọ̀rọ̀. 2 Ó ní: “OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún ìwọ Baruku pé, 3 ò ń sọ pé, o gbé, nítorí pé OLUWA ti fi ìbànújẹ́ kún ìrora rẹ; àárẹ̀ mú ọ nítorí ìkérora rẹ, o kò sì ní ìsinmi. 4 “Èmi ń wó ohun tí mo kọ́ lulẹ̀, mo sì ń tu ohun tí mo gbìn, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ gbogbo ilẹ̀ náà rí. 5 Ìwọ ń wá nǹkan ńlá fún ara tìrẹ? Má wá nǹkan ńlá fún ara rẹ. Wò ó, n óo mú kí ibi bá gbogbo eniyan, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀; ṣugbọn n óo jẹ́ kí o máa sá àsálà ní gbogbo ibi tí o bá ń lọ.” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria