Isaiah 9 - Yoruba BibleỌba Lọ́la 1 Ṣugbọn kò ní sí ìṣúdudu fún ẹni tí ó wà ninu ìnira. Ní ìgbà àtijọ́, ó sọ ilẹ̀ Sebuluni ati ilẹ̀ Nafutali di yẹpẹrẹ, ṣugbọn nígbà ìkẹyìn yóo ṣe ilẹ̀ àwọn tí ó ń gbé apá ọ̀nà òkun lógo, títí lọ dé òdìkejì odò Jọdani, ati Galili níbi tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé. 2 Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri. 3 Ó ti bukun orílẹ̀-èdè náà. Ó ti fi kún ayọ̀ wọn; wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ̀, bí ayọ̀ ìgbà ìkórè. Bí inú àwọn eniyan ti máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń pín ìkógun. 4 Nítorí pé ó ti ṣẹ́ àjàgà tí ó wọ̀ wọ́n lọ́rùn, ati ọ̀pá tí wọn fí ń ru ẹrù sí èjìká, ati kùmọ̀ àwọn tí ń fìyà jẹ wọ́n. Ó ti ṣẹ́ wọn, bí ìgbà tí ó ṣẹ́ ti àwọn ará Midiani. 5 Gbogbo bàtà àwọn ológun, tí ń kilẹ̀ lójú ogun, ati gbogbo ẹ̀wù tí wọ́n ti yí mọ́lẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀ ni a óo dáná sun, iná yóo sì jó wọn run. 6 Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fún wa ní ọmọkunrin kan. Òun ni yóo jọba lórí wa. A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ-Aládé alaafia. 7 Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i, alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi. Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀, yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo, láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí OLUWA yóo Jẹ Israẹli Níyà 8 OLUWA ranṣẹ ìdájọ́ sí Jakọbu, àní, sórí àwọn ọmọ Israẹli. 9 Gbogbo eniyan ni yóo mọ̀, àwọn ará Efuraimu ati àwọn ará Samaria, àwọn tí wọn ń fọ́nnu pẹlu ìgbéraga pé: 10 Ṣé bíríkì ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé tí ó wó lulẹ̀? Òkúta gbígbẹ́ ni a óo fi tún wọn kọ́. Igi sikamore ni a fi kọ́ èyí tí wọ́n dà wó, ṣugbọn igi kedari dáradára ni a óo lò dípò wọn. 11 Nítorí náà OLUWA ti gbé ọ̀tá dìde sí wọn: Ó ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè sí wọn: 12 Àwọn ará Siria láti ìhà ìlà oòrùn, ati àwọn ará Filistia láti ìhà ìwọ̀ oòrùn; wọn óo gbé Israẹli mì. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró. 13 Sibẹsibẹ àwọn ọmọ Israẹli kò pada sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó jẹ wọ́n níyà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò wá OLUWA àwọn ọmọ-ogun. 14 Nítorí náà, OLUWA yóo fi ìyà jẹ Israẹli. Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, yóo gé Israẹli lórí ati nírù. 15 Àwọn àgbààgbà ati àwọn ọlọ́lá wọn ni orí, àwọn wolii tí ń kọ́ àwọn eniyan ní ẹ̀kọ́ èké sì ni ìrù 16 Àwọn tí ń darí àwọn eniyan wọnyi ń ṣì wọ́n lọ́nà ni, àwọn tí wọn ń tọ́ sọ́nà sì ń já sinu ìparun. 17 Nítorí náà, OLUWA kò láyọ̀ lórí àwọn ọdọmọkunrin wọn, àánú àwọn aláìníbaba ati àwọn opó wọn kò sì ṣe é nítorí pé aṣebi ni gbogbo wọn, wọn kò sì mọ Ọlọrun, ọ̀rọ̀ burúkú ni wọ́n sì ń fi ẹnu wọn sọ. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró. 18 Ìwà burúkú wọn ń jó bí iná, tí ń jó ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn. Ó ń jó bíi igbó ńlá, ó sì ń yọ èéfín sókè lálá. 19 Nítorí ibinu OLUWA àwọn ọmọ ogun, ilẹ̀ náà jóná, àwọn eniyan ibẹ̀ dàbí èpò tí a dà sinu iná ẹnikẹ́ni kò sì dá ẹnìkejì rẹ̀ sí. 20 Wọ́n ń já nǹkan gbà lọ́tùn-ún, wọ́n ń jẹ ẹ́, sibẹ ebi ń pa wọ́n. Wọ́n ń jẹ àjẹrun lósì, sibẹ wọn kò yó, àwọn eniyan sì ń pa ara wọn jẹ. 21 Àwọn ará Manase ń bá àwọn ará Efuraimu jà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Efuraimu náà ń bá àwọn ará Manase jà. Àwọn mejeeji wá dojú ìjà kọ Juda. Sibẹsibẹ inú OLUWA kò rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò dáwọ́ ìjà rẹ̀ dúró. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria