Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Isaiah 61 - Yoruba Bible


Ìròyìn Ayọ̀ Ìdáǹdè

1 Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi, nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí, láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára. Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu, kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn, kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.

2 Ó ní kí n máa kéde ọdún ojurere OLUWA, ati ọjọ́ ẹ̀san Ọlọrun wa; kí n sì máa tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ninu.

3 Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni, ní inú dídùn dípò ìkáàánú, kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́, kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo, tí OLUWA gbìn, kí á lè máa yìn ín lógo.

4 Wọn óo tún àlàpà ahoro àtijọ́ kọ́, wọn óo tún gbogbo ilé tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́, wọn óo sì tún ìlú tí a ti parun láti ọdún gbọọrọ kọ́.

5 Àwọn àjèjì ni yóo máa ba yín bọ́ agbo ẹran yín, àwọn ni yóo sì máa ṣe alágbàṣe ninu ọgbà àjàrà yín;

6 ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA, àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa. Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo.

7 Dípò ìtìjú ìpín tiyín yóo jẹ́ meji, dípò àbùkù ẹ óo láyọ̀ ninu ìpín tí ó kàn yín. Ìlọ́po meji ni ìpín yín yóo jẹ́ ninu ilẹ̀ yín, ayọ̀ ayérayé yóo sì jẹ́ tiyín.

8 OLUWA ní, “Nítorí pé mo fẹ́ ẹ̀tọ́, mo sì kórìíra ìfipá jalè ati ohun tí kò tọ́. Dájúdájú n óo san ẹ̀san fún wọn, n óo sì bá wọn dá majẹmu ayérayé.

9 Àwọn ọmọ wọn yóo dá yàtọ̀ láàrin orílẹ̀-èdè, a óo dá arọmọdọmọ wọn mọ̀ láàrin àwọn eniyan, gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn, yóo gbà pé èmi OLUWA ti bukun wọn.”

10 N óo máa yọ̀ ninu OLUWA, ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi. Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù, ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ; bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì.

11 Bí ilẹ̀ tíí mú kí ewéko hù jáde, tí ọgbà sì ń mú kí ohun tí a gbìn sinu rẹ̀ hù, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA Ọlọrun yóo mú kí òdodo ati orin ìyìn yọ jáde níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan