Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Isaiah 57 - Yoruba Bible


OLUWA Dá Ìwà Ìbọ̀rìṣà Israẹli lẹ́bi

1 Olódodo ń ṣègbé, kò sí ẹni tí ó fi ọkàn sí i. A mú àwọn olótìítọ́ kúrò, kò sì sí ẹni tí ó yé, pé à ń yọ olódodo kúrò ninu ìdààmú ni.

2 Àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà òtítọ́, wọn óo wà ní alaafia, wọn óo máa sinmi lórí ibùsùn wọn.

3 Ẹ̀yin ọmọ oṣó wọnyi, ẹ súnmọ́bí fún ìdájọ́, ẹ̀yin ọmọ alágbèrè ati panṣaga.

4 Ta ni ẹ̀ ń fi ṣe ẹlẹ́yà? Ta ni ẹ̀ ń ya ẹnu ní ìyàkuyà sí tí ẹ yọ ṣùtì sí? Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yín irú ọmọ ẹ̀tàn;

5 ẹ̀yin tí ẹ kún fún ìṣekúṣe lábẹ́ igi Oaku, ati lábẹ́ gbogbo igi eléwé tútù. Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ yín láàrin àfonífojì, ati ní abẹ́ àpáta?

6 Àwọn oriṣa láàrin àwọn òkúta ọ̀bọ̀rọ́, ninu àfonífojì, àwọn ni ẹ̀ ń sìn, àwọn ni ò ń da ẹbọ ohun mímu lé lórí, àwọn ni ò ń fi nǹkan jíjẹ rúbọ sí. Ṣé àwọn nǹkan wọnyi ni yóo mú kí inú mi yọ́?

7 Lórí òkè gíga fíofío, ni o lọ tẹ́ ibùsùn rẹ sí níbẹ̀ ni o tí ń lọ rú ẹbọ.

8 O gbé ère oriṣa kalẹ̀ sí ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ati ẹ̀yìn òpó ìlẹ̀kùn. O kọ̀ mí sílẹ̀, o bọ́ sórí ibùsùn, o tẹ́ ibùsùn tí ó fẹ̀. O wá bá àwọn tí ó wù ọ́ da ọ̀rọ̀ pọ̀, ẹ̀ ń bá ara yín lòpọ̀.

9 O gbọ̀nà, o lọ gbé òróró fún oriṣa Moleki, o kó ọpọlọpọ turari lọ, o rán àwọn ikọ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, o sì ranṣẹ lọ sinu isà òkú pẹlu.

10 Àárẹ̀ mú ọ nítorí ìrìn àjò rẹ jìnnà, sibẹsibẹ o kò sọ fún ara rẹ pé, “Asán ni ìrìn àjò yìí.” Ò ń wá agbára kún agbára, nítorí náà àárẹ̀ kò mú ọ.

11 Ta ni ń já ọ láyà, tí ẹ̀rù rẹ̀ bà ọ́, tí o fi purọ́; tí o kò ranti mi, tí o kò sì ronú nípa mi? Ṣé nítorí mo ti dákẹ́ fún ìgbà pípẹ́, ni o kò fi bẹ̀rù mi?

12 N óo sọ nípa òdodo rẹ ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, ṣugbọn wọn kò ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́.

13 Nígbà tí o bá kígbe, kí àwọn ère tí o kó jọ gbà ọ́. Atẹ́gùn lásán ni yóo gbé gbogbo wọn lọ Afẹ́fẹ́ ni yóo fẹ́ wọn lọ. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sá di mí, ni yóo ni ilẹ̀ náà, òun ni yóo sì jogún òkè mímọ́ mi.


Ọlọrun Ṣe Ìlérí Ìrànlọ́wọ́ ati Ìwòsàn

14 OLUWA ní, “Ẹ la ọ̀nà, ẹ la ọ̀nà, ẹ tún ọ̀nà ṣe, ẹ mú gbogbo ohun ìkọsẹ̀ kúrò lọ́nà àwọn eniyan mi.”

15 Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ, ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́: òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́, ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀. Láti sọ ọkàn wọn jí.

16 Nítorí n kò ní máa jà títí ayé, tabi kí n máa bínú nígbà gbogbo: nítorí láti ọ̀dọ̀ mi ni ẹ̀mí ti ń jáde, Èmi ni mo dá èémí ìyè.

17 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ojúkòkòrò rẹ̀, inú bí mi, mo jẹ ẹ́ níyà, mo fojú pamọ́, inú sì bí mi; sibẹ ó túbọ̀ ń ṣìnà sí i ni, ó ń ṣe tinú rẹ̀.

18 Mo ti rí bí ó ti ń ṣe, ṣugbọn n óo ṣì wò ó sàn; n óo máa darí rẹ̀, n óo tù ú ninu, n óo sì fún àwọn tí ó bá ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli ní orin ayọ̀.

19 Alaafia ni, alaafia ni fún àwọn tí ó wà ní òkèèrè, ati àwọn tí ó wà nítòsí; n óo sì wò wọ́n sàn.

20 Ṣugbọn àwọn eniyan burúkú dàbí ríru omi òkun, nítorí òkun kò lè sinmi, omi rẹ̀ a sì máa rú pàǹtí ati ẹrẹ̀ sókè.

21 Kò sí alaafia fún àwọn eniyan burúkú.” Ọlọrun mi ló sọ bẹ́ẹ̀.

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan