Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

Isaiah 56 - Yoruba Bible


Gbogbo Orílẹ̀-Èdè ni yóo Wà lára Àwọn Eniyan Ọlọrun

1 OLUWA ní: “Ẹ máa dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́, kí ẹ sì máa ṣe òdodo; nítorí ìgbàlà mi yóo dé láìpẹ́, ẹ óo sì rí ìdáǹdè mi.

2 Ayọ̀ ń bẹ fún gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ati fún ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé e, tí ó ń ṣọ́ra, tí kò rú òfin ọjọ́ ìsinmi, tí kò sì fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe nǹkan burúkú.”

3 Kí àjèjì tí ó faramọ́ OLUWA má sọ pé, “Dájúdájú OLUWA yóo yà mí kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀.” Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé, “Wò ó! Mo dàbí igi gbígbẹ.”

4 Nítorí OLUWA ní, “Bí ìwẹ̀fà kan bá pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, tí ó bá ṣe ohun tí mo fẹ́, tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,

5 n óo fún wọn ní ipò láàrin àgbàlá mi, ati ìrántí tí ó dára, ju ọmọkunrin ati ọmọbinrin lọ. Orúkọ tí kò ní parẹ́ laelae, ni n óo fún wọn.

6 “Àwọn àjèjì tí ó bá darapọ̀ mọ́ OLUWA, tí wọn ń sìn ín, tí wọn fẹ́ràn rẹ̀, tí wọn sì ń ṣe iranṣẹ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, tí kò sọ ọ́ di ohun ìríra, tí ó sì di majẹmu mi mú gbọningbọnin,

7 n óo mú wọn wá sí orí òkè mímọ́ mi, n óo jẹ́ kí inú wọn máa dùn ninu ilé adura mi. Ọrẹ sísun ati ẹbọ wọn, yóo jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi; nítorí ilé adura fún gbogbo eniyan, ni a óo máa pe ilé mi.”

8 OLUWA Ọlọrun tí ń kó àwọn tí ogun túká ní Israẹli jọ sọ pé, “N óo tún kó àwọn mìíràn jọ, kún àwọn tí mo ti kọ́ kó jọ.”


A ti Dá Àwọn Olórí Israẹli lẹ́bi

9 Gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti òkèèrè, ẹ máa bọ̀, gbogbo yín ẹ máa bọ̀ bí ẹranko inú ìgbẹ́, ẹ wá jẹ àjẹrun.

10 Afọ́jú ni àwọn aṣọ́de Israẹli gbogbo wọn kò mọ nǹkankan. Ajá tí ó yadi ni wọ́n, wọn kò lè gbó; oorun ni wọ́n fẹ́ràn. Wọn á dùbúlẹ̀, wọn á máa lá àlá.

11 Wọ̀bìà ni wọ́n, alájẹkì, wọn kì í yó. Àwọn olùdarí wọn pàápàá kò mọ nǹkankan. Gbogbo wọn ti tẹ̀ sí ọ̀nà ara wọn, olukuluku wọn ń wá èrè fún ara rẹ̀.

12 Wọn á máa sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á mu waini, ẹ jẹ́ kí á mu ọtí líle ní àmuyó, bí òní ṣe rí ni ọ̀la yóo rí, yóo dùn tayọ.”

Bible Society of Nigeria © 1900/2010

Bible Society of Nigeria
Lean sinn:



Sanasan