Isaiah 53 - Yoruba Bible1 Ta ló lè gba ìyìn tí a rò gbọ́? Ta ni a ti fi agbára OLUWA hàn? 2 Ó dàgbà níwájú rẹ̀ bí nǹkan ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ rúwé ati bíi gbòǹgbò láti inú ilẹ̀ gbígbẹ. Ìrísí rẹ̀ kò dára, ojú rẹ̀ kò fanimọ́ra, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹwà tí ìbá fi wu eniyan. 3 Àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀; ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí ó sì mọ ìkáàánú ni. Ó dàbí ẹni tí àwọn eniyan ń wò ní àwòpajúdà. A kẹ́gàn rẹ̀, a kò sì kà á kún. 4 Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ, ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa; sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà, tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. 5 Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa, wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa; ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia, nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá. 6 Gbogbo wa ti ṣáko lọ bí aguntan, olukuluku wa yà sí ọ̀nà tirẹ̀, OLUWA sì ti kó ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo wa lé e lórí. 7 Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú, sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀, wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa, ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀. 8 Wọ́n mú un lọ tipátipá, lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́, ta ni ninu ìran rẹ̀ tí ó ṣe akiyesi pé wọ́n ti pa á run lórí ilẹ̀ alààyè, ati pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi, ni wọ́n ṣe nà án? 9 Wọ́n tẹ́ ẹ sí ibojì, pẹlu àwọn eniyan burúkú, wọ́n sì sin ín pẹlu ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe ẹnikẹ́ni níbi, kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. 10 Sibẹsibẹ, ó wu OLUWA láti pa á lára, ó sì fi í sinu ìbànújẹ́, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; yóo fojú rí ọmọ rẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ yóo sì gùn. Ìfẹ́ OLUWA yóo ṣẹ lọ́wọ́ rẹ̀. 11 Yóo rí èrè àníyàn ọkàn rẹ̀, yóo sì tẹ́ ẹ lọ́rùn; nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi, olódodo, yóo dá ọpọlọpọ eniyan láre, yóo sì ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 12 Nítorí náà, n óo fún un ní ìpín, láàrin àwọn eniyan ńlá, yóo sì bá àwọn alágbára pín ìkógun, nítorí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún ikú, wọ́n sì kà á mọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Sibẹsibẹ ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ eniyan, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria