Isaiah 50 - Yoruba Bible1 OLUWA ní: OLUWA ní: “Ìwé ìkọ̀sílẹ̀ tí mo fi kọ àwọn eniyan mi sílẹ̀ dà? Ta ni mo tà yín fún, tí mo jẹ lówó? Ẹ wò ó! Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ni a ṣe tà yín, nítorí àìdára yín ni mo ṣe kọ̀ yín sílẹ̀. 2 “Kí ló dé tí mo wá àwọn eniyan mi tí n kò rí ẹnìkan; mo pè, ẹnikẹ́ni kò dá mi lóhùn? Ṣé n kò lágbára tó láti rà wọ́n pada ni; àbí n kò lágbára láti gba ni là? Wò ó! Ìbáwí lásán ni mo fi gbẹ́ omi òkun, tí mo sì fi sọ odò tí ń ṣàn di aṣálẹ̀, omi wọn gbẹ, òùngbẹ gbẹ àwọn ẹja inú wọn pa, wọ́n kú, wọ́n sì ń rùn. 3 Mo da òkùnkùn bo ojú ọ̀run bí aṣọ, mo ṣe aṣọ ọ̀fọ̀ ní ìbora fún wọn.” Ìgbọràn Iranṣẹ OLUWA 4 OLUWA Ọlọrun ti fi ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sí mi lẹ́nu. Kí n lè mọ bí a tií gba àwọn tí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì níyànjú. Ojoojumọ ni ó ń ṣí mi létí láràárọ̀, kí n lè máa gbọ́rọ̀ bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́. 5 OLUWA Ọlọrun ti ṣí mi létí, n kò sì ṣe oríkunkun, tabi kí n pada sẹ́yìn. 6 Mo tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ fún àwọn tí ń nani lẹ́gba; mo sì kọ ẹ̀rẹ̀kẹ́ sí àwọn tí ń fa eniyan ní irùngbọ̀n tu. N kò fojú pamọ́ nítorí ẹ̀gàn, bẹ́ẹ̀ ni n kò gbójú sá fún itọ́ títu síni lójú. 7 OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́, nítorí náà ojú kò tì mí; nítorí náà mo múra gírí, mo jẹ́ kí ojú mi le koko, mo sì mọ̀ pé ojú kò ní tì mí. 8 Ẹni tí yóo dá mi láre wà nítòsí, ta ló fẹ́ bá mi jà? Ta ló fẹ́ fi ẹ̀sùn kàn mí? Kí olúwarẹ̀ súnmọ́ tòsí mi, kí á jọ kojú ara wa? 9 Wò ó! OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́, ta ni yóo dá mi lẹ́bi? Gbogbo wọn ni yóo gbọ̀n dànù bí aṣọ, kòkòrò yóo sì jẹ wọ́n. 10 Ta ló bẹ̀rù OLUWA ninu yín, tí ń gbọ́ràn sí iranṣẹ rẹ̀ lẹ́nu, tí ń rìn ninu òkùnkùn, tí kò ní ìmọ́lẹ̀, ṣugbọn sibẹ, tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, tí ó fẹ̀yìn ti Ọlọrun rẹ̀. 11 Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dáná, tí ẹ tan iná yí ara yín ká, ẹ máa rìn lọ ninu iná tí ẹ dá; ẹ máa la iná tí ẹ fi yí ara yín ká kọjá. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fun yín. Ẹ óo wà ninu ìrora. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria