Isaiah 46 - Yoruba Bible1 “Oriṣa Bẹli tẹríba, oriṣa Nebo doríkodò. Orí àwọn ẹran ọ̀sìn ati mààlúù ni àwọn oriṣa wọn wà. Àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rù kiri wá di ẹrù, tí àwọn ẹranko tí ó ti rẹ̀ ń rù. 2 Àwọn mejeeji jọ tẹríba, wọ́n jọ doríkodò, wọn ò lè gba àwọn ẹrù wọn kalẹ̀. Àwọn pàápàá yóo lọ sí ìgbèkùn. 3 “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu, ati gbogbo ará ilé Israẹli tí ó ṣẹ́kù; ẹ̀yin tí mo pọ̀n láti ọjọ́ tí wọ́n ti bi yín, tí mo sì gbé láti inú oyún. 4 Èmi náà ni, títí di ọjọ́ ogbó yín, n óo gbé yín títí tí ẹ óo fi hewú lórí. Èmi ni mo da yín, n óo sì máa tọ́jú yín, n óo máa gbé yín, n óo sì gbà yín là. 5 “Ta ni ẹ óo fi mí wé? Ta ni ẹ óo fi díwọ̀n mi? Ta ni ẹ lè fi wé mi, kí á lè jọ jẹ́ bákan náà? 6 Àwọn kan ń kó ọpọlọpọ wúrà jáde ninu àpò, wọ́n sì ń wọn fadaka lórí ìwọ̀n. Wọ́n sanwó ọ̀yà fún alágbẹ̀dẹ wúrà, ó bá wọn fi dá oriṣa. Wọ́n wá ń foríbalẹ̀ fún un, wọ́n ń sìn ín. 7 Wọn á gbé e lé èjìká wọn, wọn á gbé e sípò rẹ̀, á sì dúró kabẹ̀. Kò ní le kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkankan. Bí eniyan bá ké pè é, kò lè gbọ́, kò lè yọ eniyan ninu ìṣòro rẹ̀. 8 “Ẹ ranti èyí, kí ẹ dà á rò, ẹ fi ọkàn rò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀. 9 Ẹ ranti àwọn nǹkan ti àtijọ́, nítorí pé èmi ni Ọlọrun, kò sí Ọlọrun mìíràn mọ́. Èmi ni Ọlọrun, kò sí ẹni tí ó dà bí mi. 10 Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni èmi tíí sọ ohun tí ó gbẹ̀yìn. Láti ìgbà àtijọ́, ni mo tí ń sọ àwọn nǹkan tí kò ì tíì ṣẹlẹ̀. Èmi a máa sọ pé: ‘Àbá mi yóo ṣẹ, n óo sì mú ìpinnu mi ṣẹ.’ 11 Mo pe idì láti ìlà oòrùn, mo sì ti pe ẹni tí yóo mú àbá mi ṣẹ láti ilẹ̀ òkèèrè wá. Mo ti sọ̀rọ̀, n óo sì mú un ṣẹ, mo ti ṣe ìpinnu, n óo sì ṣe é. 12 “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin aláìgbọràn, ẹ̀yin tí ẹ jìnnà sí ìgbàlà. 13 Mo mú ìdáǹdè mi wá sí tòsí, kò jìnnà mọ́, ìgbàlà mi kò ní pẹ́ dé. N óo fi ìgbàlà mi sí Sioni, fún Israẹli, ògo mi.” |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria