Isaiah 38 - Yoruba BibleÀìsàn Hesekaya ati Ìmúláradá Rẹ̀ 1 Ní àkókò náà, Hesekaya ṣàìsàn, àìsàn náà pọ̀; ó fẹ́rẹ̀ kú. Aisaya wolii, ọmọ Amosi tọ̀ ọ́ wá ní ọjọ́ kan, ó wí fún un pé: “OLUWA ní kí n sọ fún ọ pé kí o ṣe ètò ilé rẹ, nítorí pé o óo kú ni, o kò ní yè.” 2 Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó gbadura sí OLUWA, 3 ó ní, “OLUWA, dákun, mo bẹ̀ ọ́ ni, ranti bí mo ti ṣe fi tọkàntọkàn rìn níwájú rẹ pẹlu òtítọ́ inú, tí mo sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ.” Hesekaya bá sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn. 4 OLUWA bá sọ fún Aisaya pé 5 kí ó lọ sọ fún Hesekaya pé, òun, OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀. Oun ti rí omijé rẹ̀, òun óo sì fi ọdún mẹẹdogun kún ọjọ́ ayé rẹ̀. 6 OLUWA ní òun óo gba Hesekaya lọ́wọ́ ọba Asiria, òun óo gbèjà ìlú Jerusalẹmu, òun óo sì dáàbò bò ó. 21 Aisaya bá sọ fún Hesekaya pé kí wọn bá a wá èso ọ̀pọ̀tọ́ kí wọn lọ̀ ọ́, kí wọn fi lé ojú oówo tí ó mú un, kí ó lè gbádùn. 22 Hesekaya bá bèèrè pé, kí ni àmì tí òun óo fi mọ̀ pé òun óo tún fi ẹsẹ̀ òun tẹ ilé Olúwa? 7 Aisaya ní, àmì tí OLUWA fún Hesekaya tí yóo mú kí ó dá a lójú pé òun OLUWA yóo ṣe ohun tí òun ṣèlérí nìyí: 8 Òun óo mú kí òjìji oòrùn ìrọ̀lẹ́ pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi. Oòrùn bá yí pada nítòótọ́, òjìji sì pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀. Orin Ọpẹ́ tí Hesekaya kọ 9 Orin tí Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nígbà tí ó ṣàìsàn tí Ọlọrun sì wò ó sàn nìyí: 10 Mo ti rò pé n óo kú lọ́jọ́ àìpé, ati pé a óo sé mi mọ́ inú ibojì, níbẹ̀ ni n óo sì ti lo ìyókù ọjọ́ ayé mi. 11 Mo rò pé n kò ní tún fojú kan OLUWA mọ́ ní ilẹ̀ alààyè, ati pé n kò ní sí láàyè mọ́ láti tún fi ojú mi kan ẹnikẹ́ni. 12 A tú àgọ́ mi palẹ̀ bí àgọ́ darandaran, a sì ká a lọ kúrò lọ́dọ̀ mi. Mo ká ayé mi bí aṣọ tí wọn ń hun. Ó sì gé mi kúrò bí aṣọ tí wọ́n gé kúrò lórí òfì. Mo ti kọ́ rò pé tọ̀sán-tòru ni ìwọ OLUWA ń fi òpin sí ayé mi. 13 Mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́ títí ilẹ̀ fi mọ́ ó fọ́ gbogbo egungun mi bí kinniun ti máa ń fọ́ egungun. Tọ̀sán-tòru mo rò pé Ọlọrun ń fi òpin sí ayé mi ni. 14 Ọkàn mi ń ṣe hílàhílo bí ẹyẹ aláàpáǹdẹ̀dẹ̀ ati ẹyẹ àkọ̀, mò ń ké igbe arò bí àdàbà. Mo wòkè títí ojú ń ro mí, ara ń ní mí, OLUWA, nítorí náà ṣe ààbò mi. 15 Ṣugbọn kí ni mo lè sọ? Nítorí pé ó ti bá mi sọ̀rọ̀, òun fúnrarẹ̀ ni ó sì ṣe é Oorun kò kùn mí nítorí pé ọkàn mi bàjẹ́. 16 OLUWA, nǹkan wọnyi ni ó mú eniyan wà láàyè, ninu gbogbo rẹ̀ èmi náà yóo wà láàyè. Áà, jọ̀wọ́ wò mí sàn, kí o mú mi wà láàyè. 17 Nítorí ìlera mi ni mo ṣe ní ìbànújẹ́ lọpọlọpọ; ìwọ ni o dì mí mú, tí n kò fi jìn sinu kòtò ìparun, nítorí o ti sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi di ohun ìgbàgbé. 18 Ibojì kò lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ikú kò lè yìn ọ́; kò sí ìrètí mọ́ fún àwọn tí wọ́n ti lọ sinu isà òkú, wọn kò lè gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ mọ́. 19 Alààyè, àní alààyè, ni ó lè máa yìn ọ́ bí mo ti yìn ọ́ lónìí. Baba a máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, nípa òdodo rẹ. 20 OLUWA yóo gbà mí là, a óo fi àwọn ohun èlò orin olókùn kọrin ninu ilé OLUWA, ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria