Isaiah 15 - Yoruba BibleOLUWA yóo Pa Moabu Run 1 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ nípa ilẹ̀ Moabu nìyí: Nítorí tí a wó ìlú Ari ati Kiri lulẹ̀ ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo, ó parí fún Moabu. 2 Àwọn ọmọbinrin Diboni ti gun àwọn ibi pẹpẹ tí wọ́n ti ń bọ̀rìṣà lọ, wọ́n lọ sọkún. Moabu ń pohùnréré ẹkún nítorí Nebo ati Medeba. Gbogbo orí wọn pá, wọ́n sì ti fá gbogbo irùngbọ̀n wọn. 3 Wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora ní ìta gbangba. Gbogbo wọn dúró lórí òrùlé ilé wọn, ati ní gbogbo gbàgede, wọ́n ń pohùnréré ẹkún, omijé sì ń dà lójú wọn. 4 Heṣiboni ati Eleale ń kígbe lóhùn rara, àwọn ará Jahasi gbọ́ ariwo wọn; nítorí náà àwọn ọmọ ogun Moabu sọkún, ọkàn rẹ̀ sì wárìrì. 5 Ọkàn mi sọkún fún Moabu; àwọn ìsáǹsá rẹ̀ sá lọ sí Soari ati Egilati Ṣeliṣiya. Ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Luhiti, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ, wọ́n sì ń kígbe arò bí wọ́n tí ń lọ sí Horonaimu. 6 Àwọn odò Nimrimu di aṣálẹ̀, koríko ibẹ̀ gbẹ; àwọn ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ jóná mọ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ewé kò rú mọ́. 7 Nítorí náà àwọn ohun tí wọ́n ní lọpọlọpọ ati ohun ìní tí wọn ti kó jọ, ni wọ́n kó lọ sí ìkọjá odò Wilo. 8 Nítorí ariwo kan ti gba gbogbo ilẹ̀ Moabu kan, ẹkún náà dé Egilaimu, ìpohùnréré náà sì dé Beerelimu. 9 Nítorí odò Diboni kún fún ẹ̀jẹ̀, sibẹsibẹ n óo jẹ́ kí ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ dé bá a. Kinniun ni yóo pa àwọn ará Moabu tí ó bá ń sá lọ ati àwọn eniyan tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria