Heberu 3 - Yoruba BibleJesu Ju Mose Lọ 1 Nítorí náà, ẹ̀yin ará ninu Oluwa, tí a jọ ní ìpín ninu ìpè tí ó ti ọ̀run wá, ẹ ṣe akiyesi Jesu, tíí ṣe òjíṣẹ́ ati Olórí Alufaa ìjẹ́wọ́ igbagbọ wa. 2 Ẹ rí i pé ó ṣe olóòótọ́ sí Ọlọrun tí ó yàn án gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣe oloòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun. 3 Nítorí bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti ní ọlá ju ilé tí ó kọ́ lọ, bẹ́ẹ̀ ni Jesu yìí ní ọlá ju Mose lọ. 4 Nítorí kò sí ilé kan tí kò jẹ́ pé eniyan ni ó kọ́ ọ. Ṣugbọn Ọlọrun ni ó ṣe ohun gbogbo. 5 Mose ṣe olóòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ. A rán an láti jẹ́rìí sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun yóo fi fún un láti sọ ni. 6 Ṣugbọn Kristi ṣe olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ninu ìdílé rẹ̀. Àwa gan-an ni ìdílé rẹ̀ náà, bí a bá dúró pẹlu ìgboyà tí à ń ṣògo lórí ìrètí wa. Ìsinmi fún Àwọn Eniyan Ọlọrun 7 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí, “Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀, 8 ẹ má ṣe agídí, gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ìṣọ̀tẹ̀, ní àkókò ìdánwò ninu aṣálẹ̀, 9 nígbà tí àwọn baba-ńlá yín dán mi wò, tí wọ́n fi rí iṣẹ́ mi fún ogoji ọdún. 10 Nítorí náà, mo bínú sí ìran wọn. Mo ní, ‘Nígbà gbogbo ni wọ́n máa ń ṣìnà ní ọkàn wọn. Iṣẹ́ mi kò yé wọn.’ 11 Ni mo bá búra pẹlu ibinu, pé wọn kò ní dé ibi ìsinmi mi.” 12 Ẹ kíyèsára, ará, kí ó má ṣe sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí yóo ní inú burúkú tóbẹ́ẹ̀ ti kò ní ní igbagbọ, tí yóo wá pada kúrò lẹ́yìn Ọlọrun alààyè. 13 Ṣugbọn ẹ máa gba ara yín níyànjú lojoojumọ níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ “Òní” tí Ìwé Mímọ́ sọ bá ti bá àwa náà wí, kí ẹ̀ṣẹ̀ má baà tan ẹnikẹ́ni lọ, kí ó sì mú kí ó ṣe agídí sí Ọlọrun. 14 Nítorí a ti di àwọn tí ó ń bá Kristi kẹ́gbẹ́ bí a bá fi ọkàn tán an títí dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti fi ọkàn tán an ní ìbẹ̀rẹ̀ igbagbọ wa. 15 Bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe agídí gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ọ̀tẹ̀.” 16 Mò ń bèèrè, àwọn ta ni ó gbọ́ tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀? Ṣebí gbogbo àwọn tí wọ́n bá Mose jáde kúrò ní Ijipti ni. 17 Àwọn ta ni Ọlọrun bínú sí ní ogoji ọdún? Ṣebí àwọn tí ó ṣẹ̀ ni, tí òkú wọn wà káàkiri ní aṣálẹ̀. 18 Àwọn ta ni ó búra pé wọn kò ní wọ inú ìsinmi òun? Ṣebí àwọn aláìgbọràn ni. 19 A rí i pé wọn kò lè wọ inú ìsinmi yìí nítorí wọn kò gbàgbọ́. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria