Gẹnẹsisi 3 - Yoruba BibleÌwà Àìgbọràn 1 Ejò jẹ́ alárèékérekè ju gbogbo ẹranko tí OLUWA Ọlọrun dá lọ. Ejò bi obinrin náà pé, “Ngbọ́! Ṣé nítòótọ́ ni Ọlọrun sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso àwọn igi ọgbà yìí?” 2 Obinrin náà dá a lóhùn, ó ní: “A lè jẹ ninu èso àwọn igi tí wọ́n wà ninu ọgbà, 3 àfi igi tí ó wà láàrin ọgbà nìkan ni Ọlọrun ní a kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso rẹ̀, a kò tilẹ̀ gbọdọ̀ fọwọ́ kàn án, ati pé ọjọ́ tí a bá fọwọ́ kàn án ni a óo kú.” 4 Ṣugbọn ejò náà dáhùn, ó ní, “Ẹ kò ní kú rárá, 5 Ọlọrun sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé bí ẹ bá jẹ ẹ́, ojú yín yóo là, ẹ óo sì dàbí òun alára, ẹ óo mọ ire yàtọ̀ sí ibi.” 6 Nígbà tí obinrin yìí ṣe akiyesi pé èso igi náà dára fún jíjẹ ati pé ó dùn ún wò, ó sì wòye bí yóo ti dára tó láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n, ó mú ninu èso igi náà, ó jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀, ọkọ rẹ̀ náà sì jẹ ẹ́. 7 Ojú àwọn mejeeji bá là, wọ́n sì mọ̀ pé ìhòòhò ni àwọn wà, wọ́n bá gán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sán an mọ́ ìdí. 8 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbúròó OLUWA Ọlọrun tí ń rìn ninu ọgbà. Wọ́n bá sá pamọ́ sí ààrin àwọn igi ọgbà. 9 Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun pe ọkunrin náà, ó bi í pé, “Níbo ni o wà?” 10 Ó dá Ọlọrun lóhùn, ó ní, “Nígbà tí mo gbúròó rẹ ninu ọgbà, ẹ̀rù bà mí, mo bá farapamọ́ nítorí pé ìhòòhò ni mo wà.” 11 Ọlọrun bi í pé, “Ta ló sọ fún ọ pé ìhòòhò ni o wà? Àbí o ti jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ?” 12 Ọkunrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin tí o fi tì mí ni ó fún mi ninu èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.” 13 OLUWA Ọlọrun bi obinrin náà pé, “Irú kí ni o dánwò yìí?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Ejò ni ó tàn mí tí mo fi jẹ ẹ́.” Ọlọrun Ṣèdájọ́ 14 OLUWA Ọlọrun bá sọ fún ejò náà pé, “Nítorí ohun tí o ṣe yìí, o di ẹni ìfibú jùlọ láàrin gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko. Àyà rẹ ni o óo máa fi wọ́ káàkiri, erùpẹ̀ ni o óo sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. 15 N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà, ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀. Wọn óo máa fọ́ ọ lórí, ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.” 16 Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí fún obinrin náà pé, “N óo fi kún ìnira rẹ nígbà tí o bá lóyún, ninu ìrora ni o óo máa bímọ. Sibẹsibẹ, lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóo máa fà sí, òun ni yóo sì máa ṣe olórí rẹ.” 17 Ó sọ fún Adamu, pé, “Nítorí pé o gba ohun tí aya rẹ wí fún ọ, o sì jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ, mo fi ilẹ̀ gégùn-ún títí lae nítorí rẹ. Pẹlu ìnira ni o óo máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. 18 Ẹ̀gún ati òṣùṣú ni ilẹ̀ yóo máa hù jáde fún ọ, ewéko ni o óo sì máa jẹ. 19 Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ, títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀, nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá. Erùpẹ̀ ni ọ́, o óo sì pada di erùpẹ̀.” 20 Adamu sọ iyawo rẹ̀ ní Efa, nítorí pé òun ni ìyá gbogbo eniyan. 21 OLUWA Ọlọrun fi awọ ẹranko rán aṣọ fún Adamu ati iyawo rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n. Ọlọrun Lé Adamu ati Efa jáde ninu Ọgbà 22 Lẹ́yìn náà, OLUWA Ọlọrun wí pé, “Nisinsinyii tí ọkunrin náà ti dàbí wa, tí ó sì ti mọ ire yàtọ̀ sí ibi, kí ó má lọ mú ninu èso igi ìyè, kí ó jẹ ẹ́, kí ó sì wà láàyè títí lae.” 23 Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde. 24 Ó lé e jáde, ó sì fi Kerubu kan sí ìhà ìlà oòrùn ọgbà náà láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè náà, pẹlu idà oníná tí ń jò bùlà bùlà, tí ó sì ń yí síhìn-ín sọ́hùn-ún. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria