Esteri 10 - Yoruba BibleTítóbi Ahasu-erusi ati Modekai 1 Ọba Ahasu-erusi pàṣẹ pé kí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jìnnà ati àwọn tí wọn ń gbé etíkun máa san owó orí. 2 Gbogbo iṣẹ́ agbára ati ipá rẹ̀, ati bí ó ṣe gbé Modekai ga sí ipò ọlá, ni a kọ sinu ìwé ìtàn àwọn ọba Media ati ti Pasia. 3 Modekai tíí ṣe Juu ni igbákejì sí Ahasu-erusi ọba. Ó tóbi, ó sì níyì pupọ láàrin àwọn Juu, nítorí pé ó ń wá ire àwọn eniyan rẹ̀, ó sì ń sọ̀rọ̀ alaafia fún gbogbo wọn. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria