Eksodu 37 - Yoruba BibleKíkan Àpótí Ẹ̀rí (Eks 25:10-22) 1 Besaleli fi igi akasia àpótí ẹ̀rí náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀, ó sì ga ní igbọnwọ kan ààbọ̀. 2 Ó yọ́ wúrà bò ó ninu ati lóde, ó sì tún fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀. 3 Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà, òrùka meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji. 4 Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n. 5 Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ inú àwọn òrùka tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí náà láti máa fi gbé e. 6 Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú, gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. 7 Ó sì fi wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ṣe àwọn Kerubu meji, ó jó wọn mọ́ igun kinni keji ìtẹ́ àánú náà, 8 Kerubu kinni wà ní igun kinni, Kerubu keji sì wà ní igun keji. 9 Àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú náà; wọ́n kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìtẹ́ àánú. Tabili Àkàrà Ìrúbọ sí Ọlọrun (Eks 25:23-30) 10 Ó fi igi akasia kan tabili kan; gígùn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ meji, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀. 11 Ó yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, ó sì fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀. 12 Ìgbátí tí ó ṣe náà fẹ̀ ní àtẹ́lẹwọ́ kan ati ààbọ̀. 13 Ó da òrùka wúrà mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin tabili náà lábẹ́ ìgbátí rẹ̀, 14 àwọn òrùka yìí ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé tabili náà. 15 Ó fi igi akasia ṣe ọ̀pá tí wọ́n fi máa ń gbé tabili náà, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n. 16 Wúrà ni ó fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò tí yóo máa wà lórí tabili náà: àwọn àwo pẹrẹsẹ ati àwọn àwo kòtò fún turari, abọ́, ati ife tí wọn yóo máa fi ta nǹkan sílẹ̀ fún ètùtù. Ṣíṣe Ọ̀pá Fìtílà (Eks 25:31-40) 17 Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá ìgbámú rẹ̀, àṣepọ̀ ni ó ṣe é, pẹlu àwọn fìtílà rẹ̀, ati àwọn kinní kan bí òdòdó tí ó fi dárà sí i lára. 18 Ẹ̀ka mẹfa ni ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà; mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, mẹta lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji. 19 Ó ṣe àwọn kinní kan bí òdòdó alimọndi mẹta mẹta sórí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà náà. 20 Ife mẹrin ni ó ṣe sórí ọ̀pá fìtílà náà gan-an, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí òdòdó alimọndi pẹlu ìrudi ati ìtànná rẹ̀. 21 Ìrudi kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ẹ̀ka meji meji tí ó so mọ́ ara ọ̀pá fìtílà náà lọ́nà mẹtẹẹta. 22 Àṣepọ̀ ni ó ṣe ọ̀pá fìtílà ati ẹ̀ka ara rẹ̀ ati ìrudi abẹ́ wọn; ojúlówó wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni ó fi ṣe wọ́n. 23 Fìtílà meje ni ó ṣe fún ọ̀pá náà, ojúlówó wúrà ni ó fi ṣe ọ̀pá tí a fi ń pa iná ẹnu fìtílà. 24 Odidi talẹnti wúrà marundinlaadọrin ni ó lò lórí ọ̀pá fìtílà yìí ati àwọn ohun èlò tí wọ́n jẹ mọ́ ti ọ̀pá fìtílà. Ṣíṣe Pẹpẹ fún Sísun Turari (Eks 30:1-5) 25 Ó fi igi akasia ṣe pẹpẹ turari kan, bákan náà ni gígùn ati fífẹ̀ rẹ̀ rí, wọ́n jẹ́ igbọnwọ kọ̀ọ̀kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ meji. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe é pẹlu ìwo rẹ̀ mẹrẹẹrin. 26 Ó yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, ati òkè ati ẹ̀gbẹ́ ati abẹ́ rẹ̀, ati ìwo rẹ̀ pẹlu, ó sì fi wúrà ṣe ìgbátí rẹ̀. 27 Ó da òrùka wúrà meji meji, ó jó wọn mọ́ abẹ́ ìgbátí pẹpẹ náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni-keji, òrùka wọnyi ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé pẹpẹ náà. 28 Ó fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá rẹ̀, ó sì yọ́ wúrà bò wọ́n. Ṣíṣe Òróró Ìyàsímímọ́ ati Turari (Eks 30:22-38) 29 Ó ṣe òróró ìyàsímímọ́ ati turari olóòórùn dídùn bí àwọn tí wọn ń ṣe turari ṣe máa ń ṣe é. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria