2 Kronika 4 - Yoruba BibleÀwọn Ohun Èlò Inú Tẹmpili (1A. Ọba 7:23-51) 1 Solomoni ọba ṣe pẹpẹ idẹ kan tí ó gùn ní ogún igbọnwọ (mita 9), ìbú rẹ̀ náà sì jẹ́ ogún igbọnwọ (mita 9). Ó ga ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½). 2 Ó ṣe agbada omi kan tí ó fẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½), ó sì ga ní igbọnwọ marun-un (mita 2¼). Àyíká etí rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ (mita 13½). 3 Gbogbo ẹ̀yìn agbada yìí ni ó ya àwòrán mààlúù sí ní ìlà meji meji yíká ìsàlẹ̀ etí rẹ̀. 4 Agbada yìí wà lórí ère mààlúù mejila tí wọ́n kọjú síta: mẹta kọjú sí ìhà àríwá, mẹta kọjú sí ìwọ̀ oòrùn, mẹta kọjú sí ìhà gúsù, mẹta yòókù sì kọjú sí ìlà oòrùn. 5 Agbada náà nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ dàbí etí ife omi ati bí òdòdó lílì. Agbada náà gbà tó ẹgbẹẹdogun ìwọ̀n bati omi. 6 Ó ṣe abọ́ ńlá mẹ́wàá, ó gbé marun-un ka ẹ̀gbẹ́ gúsù, ó sì gbé marun-un yòókù ka ẹ̀gbẹ́ àríwá. Àwọn abọ́ wọnyi ni wọ́n fi ń bu omi láti fọ àwọn ohun tí wọn ń lò fún ẹbọ sísun. Omi inú agbada náà sì ni àwọn alufaa máa ń lò láti fi wẹ̀. 7 Solomoni ṣe ọ̀pá fìtílà wúrà mẹ́wàá bí àpẹẹrẹ tí wọ́n fún un. Ó gbé wọn kalẹ̀ ninu tẹmpili: marun-un ní ìhà gúsù, marun-un yòókù ní ìhà àríwá. 8 Ó ṣe tabili mẹ́wàá, ó gbé wọn kalẹ̀ ninu tẹmpili: marun-un ní ìhà gúsù, marun-un yòókù ní ìhà àríwá. Ó sì ṣe ọgọrun-un àwo kòtò wúrà. 9 Ó kọ́ gbọ̀ngàn kan fún àwọn alufaa, ati òmíràn tí ó tóbi, ó ṣe ìlẹ̀kùn sí wọn, ó sì yọ́ idẹ bo àwọn ìlẹ̀kùn náà. 10 Ó gbé agbada omi kalẹ̀ sí apá gúsù ìhà ìlà oòrùn igun ilé náà. 11 Huramu mọ ìkòkò, ó rọ ọkọ́, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó ṣe sinu ilé Ọlọrun fún Solomoni ọba. 12 Àwọn iṣẹ́ náà nìwọ̀nyí: Òpó meji, àwọn ọpọ́n meji tí wọ́n dàbí abọ́ tí wọ́n wà lórí àwọn òpó náà, nǹkankan tí ó dàbí ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi dárà sára àwọn ọpọ́n tí ó wà lórí òpó náà, 13 àwọn irinwo òdòdó idẹ tí wọ́n fi ṣe ọnà ní ìlà meji meji yí ọpọ́n orí àwọn òpó náà ká. 14 Ó ṣe àwọn abọ́ ńlá ati ìjókòó wọn. 15 Ó ṣe agbada omi kan ati ère mààlúù mejila sí abẹ́ rẹ̀. 16 Ó mọ àwọn ìkòkò, ó rọ ọkọ́ ati àmúga tí wọ́n fi ń mú ẹran, ati gbogbo ohun èlò wọn. Idẹ dídán ni Huramu fi ṣe gbogbo wọn fún Solomoni ọba, fún lílò ninu ilé OLUWA. 17 Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jọdani tí ó jẹ́ ilẹ̀ amọ̀, láàrin Sukotu ati Sereda ni ọba ti ṣe wọ́n. 18 Àwọn nǹkan tí Solomoni ṣe pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí a kò fi mọ ìwọ̀n idẹ tí ó lò. 19 Solomoni ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ilé Ọlọrun: pẹpẹ wúrà, tabili fún burẹdi ìfihàn. 20 Àwọn ọ̀pá ati fìtílà tí wọ́n fi ojúlówó wúrà ṣe láti máa jò níwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ. 21 Ó fi wúrà tí ó dára jùlọ ṣe àwọn òdòdó, àwọn fìtílà ati àwọn ẹ̀mú. 22 Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ohun tí wọ́n fi ń tún òwú fìtílà ṣe ati àwọn àwo kòtò; àwọn àwo turari, ati àwọn àwo ìmúná. Wúrà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn ìta tẹmpili, ati ìlẹ̀kùn síbi mímọ́ jùlọ, ati ìlẹ̀kùn gbọ̀ngàn tẹmpili náà. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria