1 Kọrinti 11 - Yoruba Bible1 Ẹ máa fara wé mi bí èmi náà tí ń fara wé Kristi. Obinrin Níláti Bo Orí ninu Ìsìn 2 Mo yìn yín nítorí pé ẹ̀ ń ranti mi nígbà gbogbo, ati pé ẹ kò jẹ́ kí àwọn ẹ̀kọ́ tí mo fi kọ yín látijọ́ bọ́ lọ́wọ́ yín. 3 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé Kristi ni orí fún olukuluku ọkunrin, ọkunrin ni orí fún obinrin, Ọlọrun wá ni orí Kristi. 4 Ọkunrin tí ó bá ń gbadura tabi tí ó bá ń waasu tí ó bo orí fi àbùkù kan orí rẹ̀. 5 Ṣugbọn obinrin tí ó bá ń gbadura tabi tí ó bá ń waasu láì bo orí rẹ̀ fi àbùkù kan orí rẹ̀. Ó dàbí kí ó kúkú fá orí rẹ̀. 6 Nítorí bí obinrin kò bá bo orí, kí ó kúkú gé irun rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ ìtìjú fún obinrin láti gé irun rẹ̀ mọ́lẹ̀ tabi láti fá orí rẹ̀ a jẹ́ pé ó níláti bo orí rẹ̀. 7 Nítorí kò tọ́ kí ọkunrin bo orí rẹ̀, nítorí àwòrán ati ògo Ọlọrun ni. Ṣugbọn ògo ọkunrin ni obinrin. 8 Nítorí ọkunrin kò wá láti ara obinrin; obinrin ni ó wá láti ara ọkunrin. 9 Ati pé a kò dá ọkunrin nítorí obinrin, obinrin ni a dá nítorí ọkunrin. 10 Nítorí èyí, ó yẹ kí obinrin ní àmì àṣẹ ní orí nítorí àwọn angẹli. 11 Ṣugbọn ṣá, ninu Oluwa, bí obinrin ti nílò ọkunrin, bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin nílò obinrin. 12 Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ara ọkunrin ni obinrin ti wá, láti inú obinrin ni ọkunrin náà sì ti wá. Ṣugbọn ohun gbogbo ti ọ̀dọ̀ Oluwa wá. 13 Ẹ̀yin náà ẹ ro ọ̀rọ̀ ọ̀hún wò láàrin ara yín. Ǹjẹ́ ó bójú mu pé kí obinrin gbadura sí Ọlọrun láì bo orí? 14 Mo ṣebí ìṣe ẹ̀dá pàápàá kọ yín pé tí ọkunrin bá jẹ́ kí irun rẹ̀ gùn, ó fi àbùkù kan ara rẹ̀; 15 bẹ́ẹ̀ sì ni pé ohun ìyìn ni ó jẹ́ fún obinrin tí ó bá jẹ́ kí irun rẹ̀ gùn. Nítorí a fi irun gígùn fún obinrin láti bò ó lórí. 16 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ mọ̀ pé ní tiwa, a kò ní oríṣìí àṣà mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ninu àwọn ìjọ Ọlọrun. Ìwà Tí Kò Dára Nípa Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa 17 Nígbà tí mò ń sọ èyí, nǹkankan wà tí n kò yìn yín fún, nítorí nígbà tí ẹ bá péjọ, ìpéjọpọ̀ yín ń ṣe ibi ju rere lọ. 18 Nítorí, ní ọ̀nà kinni, mo gbọ́ pé nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, ìyapa a máa wà láàrin yín. Mo gbàgbọ́ pé òtítọ́ wà ninu ìròyìn yìí. 19 Nítorí ìyapa níláti wà láàrin yín, kí àwọn tí ń ṣe ẹ̀tọ́ láàrin yín lè farahàn. 20 Nítorí èyí, nígbà tí ẹ bá péjọ sí ibìkan náà, kì í ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ni ẹ̀ ń jẹ. 21 Nítorí pé ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín níí máa kánjú jẹun, ebi a máa pa àwọn kan nígbà tí àwọn mìíràn ti mu ọtí lámuyó! 22 Ṣé ẹ kò ní ilé tí ẹ ti lè máa jẹ, kí ẹ máa mu ni? Àbí ẹ fẹ́ kó ẹ̀gàn bá ìjọ Ọlọrun ni? Ẹ fẹ́ dójú ti àwọn aláìní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kí ni kí n sọ fun yín? Ṣé kí n máa yìn yín ni? Rárá o! N kò ní yìn yín fún èyí. Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa (Mat 26:26-29; Mak 14:22-25; Luk 22:14-20) 23 Nítorí láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni mo ti gba ohun tí mo fi kọ yín, pé ní alẹ́ ọjọ́ tí a fi Jesu Oluwa lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, ó mú burẹdi, 24 lẹ́yìn tí ó ti dúpẹ́ tán, ó bù ú, ó ní, “Èyí ni ara mi tí ó wà fun yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” 25 Bákan náà ni ó mú ife lẹ́yìn oúnjẹ, ó ní, “Èyí ni ife ti majẹmu titun tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá. Nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” 26 Nítorí nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ burẹdi yìí, tí ẹ sì ń mu ninu ife yìí, ẹ̀ ń kéde ikú Oluwa títí yóo fi dé. Jíjẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa Láìyẹ 27 Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń jẹ burẹdi, tabi tí ó ń mu ninu ife Oluwa láìyẹ jẹ̀bi ìlòkulò ara ati ẹ̀jẹ̀ Oluwa. 28 Kí olukuluku yẹ ara rẹ̀ wò kí ó tó jẹ ninu burẹdi, kí ó sì tó mu ninu ife Oluwa. 29 Nítorí ẹni tí ó bá ń jẹ, tí ó ń mu láìmọ ìyàtọ̀ tí ó wà ninu ara Kristi, ìdájọ́ ni ó ń jẹ, tí ó sì ń mu, lórí ara rẹ̀. 30 Nítorí èyí ni ọpọlọpọ ninu yín ṣe di aláìlera ati ọlọ́kùnrùn, tí ọpọlọpọ tilẹ̀ ti kú. 31 Ṣugbọn tí a bá ti yẹ ara wa wò, a kò ní dá wa lẹ́jọ́. 32 Ṣugbọn bí a bá bọ́ sinu ìdájọ́ Oluwa, ó fi ń bá wa wí ni, kí ó má baà dá wa lẹ́bi pẹlu àwọn yòókù. 33 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá péjọ láti jẹun, ẹ máa dúró de ara yín. 34 Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni, kí ó jẹun kí ó tó kúrò ní ilé, kí ìpéjọpọ̀ yín má baà jẹ́ ìdálẹ́bi fun yín. Nígbà tí mo bá dé, n óo ṣe ètò nípa àwọn nǹkan tí ó kù. |
Bible Society of Nigeria © 1900/2010
Bible Society of Nigeria