O. Sol 6 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníỌ̀rẹ́ 1 Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ, Ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin? Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí, kí a lè bá ọ wá a? Olólùfẹ́ 2 Olùfẹ́ mi ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọgbà rẹ̀, sí ibi ibùsùn tùràrí, láti máa jẹ nínú ọgbà láti kó ìtànná lílì jọ. 3 Èmi ni ti olùfẹ́ mi, olùfẹ́ mi sì ni tèmi, Ó ń jẹ láàrín ìtànná lílì. Olùfẹ́ 4 Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tirsa, ìwọ lẹ́wà bí i Jerusalẹmu, ìwọ ògo bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun. 5 Yí ojú rẹ kúrò lára mi; nítorí ojú rẹ borí mi. Irun rẹ rí bí i ọ̀wọ́ ewúrẹ́ tí ó sọ̀kalẹ̀ wá láti Gileadi. 6 Eyín rẹ rí bí ọ̀wọ́ àgùntàn, Tí ó gòkè láti ibi ìwẹ̀ rẹ̀ wá, gbogbo wọn bí ìbejì, kò sì ṣí ọ̀kankan tí ó yàgàn nínú wọn. 7 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́bàá ìbòjú rẹ, rí bí ẹ̀là èso pomegiranate. 8 Ọgọ́ta ayaba ní ń bẹ níbẹ̀, àti ọgọ́rin àlè, àti àwọn wúńdíá láìníye. 9 Àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, ọ̀kan ni, ọ̀kan ṣoṣo ọmọbìnrin ìyá rẹ̀, ààyò ẹyọ kan ṣoṣo ẹni tí ó bí i. Àwọn obìnrin rí i wọ́n pè é ní alábùkún fún àwọn ayaba àti àwọn àlè gbé oríyìn fún un. Ọ̀rẹ́ 10 Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀, tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn, tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun? Olùfẹ́ 11 Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ọgbà èso igi láti wo àwọn ẹ̀ka igi tuntun ní àfonífojì, láti rí i bí àjàrà rúwé, tàbí bí pomegiranate ti rudi. 12 Kí èmi tó mọ̀, àárẹ̀ ọkàn mú mi, mo sì fẹ́ kí ń wà láàrín àwọn ènìyàn mi. Ọ̀rẹ́ 13 Padà wá, padà wá, ìwọ ọmọ Ṣulami padà wá, padà wá, kí àwa kí ó lè yọ́ ọ wò. Èéṣe tí ẹ̀yin fẹ́ yọ́ Ṣulamati wò, bí ẹni pé orin ijó Mahanaimu? |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.