O. Sol 5 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníOlólùfẹ́ 1 Mo ti dé inú ọgbà mi, arábìnrin mi, ìyàwó mi; mo ti kó òjìá pẹ̀lú òórùn dídùn mi jọ. Mo ti jẹ afárá mi pẹ̀lú oyin mi; mo ti mu ọtí wáìnì mi pẹ̀lú wàrà mi. Ẹ jẹ, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ mu, àní ẹ mu àmuyó, ẹ̀yin olùfẹ́. Ọ̀rẹ́ Olùfẹ́ 2 Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí. Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn. “Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi Orí mi kún fún omi ìrì, irun mi kún fún òtútù òru.” 3 Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀? Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku? 4 Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùn inú mi sì yọ́ sí i 5 Èmi dìde láti ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, òjìá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi, òjìá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń sàn sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn 6 Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀. Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i. Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn 7 Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká. Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́; wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi. Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi! 8 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi, kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un? Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi. Ọ̀rẹ́ 9 Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ, ìwọ arẹwà jùlọ láàrín àwọn obìnrin? Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju àwọn tókù lọ tí ìwọ fi ń fi wá bú bẹ́ẹ̀? Olùfẹ́ 10 Olùfẹ́ mi ní ìtànṣán ó sì pọ́n ó ní ọlá ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ. 11 Orí rẹ̀ rí bí i wúrà tí ó dára jùlọ ìdì irun rẹ̀ rí bí i imọ̀ ọ̀pẹ ó sì dúdú bí i ẹyẹ ìwò 12 Ojú rẹ̀ rí bí i ti àdàbà ní ẹ̀bá odò tí ń sàn, tí a fi wàrà wẹ̀, tí ó jì, tí ó sì dákẹ́ rọ́rọ́ 13 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ rí bí ibùsùn tùràrí tí ó sun òórùn tùràrí dídùn Ètè rẹ̀ rí bí i ìtànná lílì ó ń kán òjìá olóòórùn dídùn 14 Apá rẹ̀ rí bí i ọ̀pá wúrà, tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí yíká Ara rẹ̀ rí bí i eyín erin dídán tí a fi safire ṣe lọ́ṣọ̀ọ́. 15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ rí bí i òpó mábù tí a gbé ka ihò ìtẹ̀bọ̀ wúrà dáradára Ìrísí rẹ̀ rí bí igi kedari Lebanoni, tí dídára rẹ̀ kò ní ẹgbẹ́. 16 Ẹnu rẹ̀ jẹ́ adùn fún ara rẹ̀ ó wu ni pátápátá. Háà! Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, Èyí ni olùfẹ́ mi, èyí sì ni ọ̀rẹ́ mi. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.