O. Daf 98 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 98 1 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa, nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀ o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un 2 Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀ o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè. 3 Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli; gbogbo òpin ayé ni ó ti rí iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa. 4 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé, ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn 5 Ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́, 6 Pẹ̀lú ìpè àti fèrè ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba. 7 Jẹ́ kí Òkun kí ó hó pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, Gbogbo ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀. 8 Ẹ jẹ́ kí odo kí ó ṣápẹ́, ẹ jẹ́ kí òkè kí ó kọrin pẹ̀lú ayọ̀; 9 Ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa Nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.