O. Daf 97 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 97 1 Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀ jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn 2 Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀. 3 Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri 4 Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn ó sì kárí ayé ayé rí i ó sì wárìrì 5 Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa, níwájú Olúwa gbogbo ayé. 6 Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀. 7 Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì, àwọn tí ń fi ère gbéraga, ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run! 8 Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn inú àwọn ilé Juda sì dùn Nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa 9 Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ. 10 Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́ ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú. 11 Ìmọ́lẹ̀ tàn sórí àwọn olódodo àti ayọ̀ nínú àlàyé ọkàn 12 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo, kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.