O. Daf 96 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 96 1 Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa: Ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé. 2 Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀ ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́ 3 Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn. 4 Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí; òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ 5 Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run 6 Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀ agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀. 7 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn Ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa 8 Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un; ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀ 9 Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀; ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé. 10 Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba” a fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí; ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn. 11 Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo jẹ́ kí pápá Òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. 12 Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀ àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀: nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀ 13 Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa, nítorí tí ó ń bọ̀ wá, Ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.