O. Daf 93 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 93 1 Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ; ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára. Ó fi ìdí ayé múlẹ̀; kò sì le è yí. 2 Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́; ìwọ wà títí ayérayé. 3 A ti gbé Òkun sókè, Olúwa, Òkun ti gbé ohùn wọn sókè; Òkun ti gbé rírú omi wọn sókè. 4 Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ, ó ni ògo ju Òkun rírú lọ Olúwa ga ní ògo. 5 Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin; ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.