Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -

O. Daf 88 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní


Saamu 88
Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti mahalati leannoti. Maskili ti Hemani ará Esra.

1 Olúwa, Ọlọ́run tí ó gbà mí là, ní ọ̀sán àti ní òru ni mo kígbe sókè sí Ọ.

2 Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ; dẹ etí rẹ sí igbe mi.

3 Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.

4 A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀ èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.

5 A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú, ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́, ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.

6 Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn, ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.

7 Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi; ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.

8 Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn. A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;

9 Ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú. Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́; mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.

10 Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi? Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?

11 A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí: Tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?

12 A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?

13 Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa; ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.

14 Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?

15 Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi, èmi múra àti kú; nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí, èmi di gbére-gbère

16 Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi; ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò

17 Ní gbogbo ọjọ́ ni wọn yí mi ká bí ìkún omi; wọ́n mù mí pátápátá.

18 Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi; òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.

A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.

Yoruba Contemporary Bible

Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®

Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.

Biblica, Inc.
Lean sinn:



Sanasan