O. Daf 75 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 75 Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Saamu ti Asafu. Orin. 1 A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run, a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí; àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ. 2 Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀; Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo. 3 Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì, Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin. 4 Èmí wí fún àwọn agbéraga pé Ẹ má ṣe gbéraga mọ́; àti sí ènìyàn búburú; Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè. 5 Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run; ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.” 6 Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá tàbí ní ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá. 7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́; Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga. 8 Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà, ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú, ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde, àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá. 9 Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé; Èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu. 10 Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú, Ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.