O. Daf 7 - Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-ÒníSaamu 7 Ṣiggaioni ti Dafidi, èyí tí ó kọ sí Olúwa nípa Kuṣi, ará Benjamini. 1 Olúwa Ọlọ́run mi, ààbò mi wà nínú rẹ; gba mí là kí o sì tú mi sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń lé mi, 2 kí wọn ó má ba à fa ọkàn mi ya gẹ́gẹ́ bí kìnnìún, wọ́n á ya á pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tí yóò gbà mí. 3 Olúwa Ọlọ́run mi, tí èmi bá ṣe èyí tí ẹ̀bi sì wà ní ọwọ́ mi 4 Bí èmi bá ṣe ibi sí ẹni tí ń wá àlàáfíà pẹ̀lú mi, tí mo ja ọ̀tá mi lólè láìnídìí: 5 Nígbà náà, jẹ́ kí ọ̀tá mi lé mi kí wọn sì mú mi; jẹ́ kí òun kí ó tẹ ọkàn mi mọ́lẹ̀ kí wọn sì mú mi sùn nínú eruku. Sela. 6 Dìde, Olúwa, nínú ìbínú rẹ; dìde lòdì sí ìrunú àwọn ọ̀tá mi. Jí, Ọlọ́run mi; kéde òdodo. 7 Kí ìpéjọ àwọn ènìyàn yíká. Jọba lórí wọn láti òkè wá; 8 Jẹ́ kí Olúwa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn. Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà òtítọ́, ẹni gíga jùlọ. 9 Ọlọ́run Olódodo, Ẹni tí ó ń wo inú àti ọkàn, tí ó ń mú òpin sí ìwà ipá ẹni búburú tí ó sì ń pa àwọn olódodo mọ́. 10 Ààbò mi ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ń ṣe ìgbàlà òtítọ́ ní àyà. 11 Ọlọ́run ni onídàájọ́ òtítọ́, Ọlọ́run tí ń sọ ìrunú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́. 12 Bí kò bá yípadà, Òun yóò pọ́n idà rẹ̀ mú; ó ti fa ọrun rẹ̀ le ná, ó ti múra rẹ̀ sílẹ̀. 13 Ó ti pèsè ohun ìjà ikú sílẹ̀; ó ti pèsè ọfà iná sílẹ̀. 14 Ẹni tí ó lóyún ohun búburú, tí ó sì lóyún wàhálà, ó bí èké jáde. 15 Ẹni tí ó gbẹ́ ọ̀fìn, tí ó kó o jáde jì sí kòtò tí ó gbẹ́ sílẹ̀. 16 Wàhálà tí ó fà padà sórí rẹ̀; Ìwà ipá rẹ̀ padà sórí ara rẹ̀. 17 Èmi ó fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí òdodo rẹ̀, Èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa Ọ̀gá-ògo jùlọ. |
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Biblica, Inc.